Quran Apps in many lanuages:

Surah Az-Zukhruf Ayahs #23 Translated in Yoruba

وَجَعَلُوا الْمَلَائِكَةَ الَّذِينَ هُمْ عِبَادُ الرَّحْمَٰنِ إِنَاثًا ۚ أَشَهِدُوا خَلْقَهُمْ ۚ سَتُكْتَبُ شَهَادَتُهُمْ وَيُسْأَلُونَ
Awon molaika, awon t’o je erusin Ajoke-aye, won tun so won di omobinrin! Se won foju ri iseda won ni? Won maa se akosile ohun ti won foju ri. Won si maa bi won leere (nipa re)
وَقَالُوا لَوْ شَاءَ الرَّحْمَٰنُ مَا عَبَدْنَاهُمْ ۗ مَا لَهُمْ بِذَٰلِكَ مِنْ عِلْمٍ ۖ إِنْ هُمْ إِلَّا يَخْرُصُونَ
Won tun wi pe: "Ti Ajoke-aye ba fe, awa iba ti josin fun won." Ko si imo kan fun won nipa iyen. Won ko si je kini kan bi ko se pe won n paro
أَمْ آتَيْنَاهُمْ كِتَابًا مِنْ قَبْلِهِ فَهُمْ بِهِ مُسْتَمْسِكُونَ
Tabi A ti fun won ni Tira kan siwaju al-Ƙur’an, ti won n lo ni eri
بَلْ قَالُوا إِنَّا وَجَدْنَا آبَاءَنَا عَلَىٰ أُمَّةٍ وَإِنَّا عَلَىٰ آثَارِهِمْ مُهْتَدُونَ
Rara. Won wi pe: "Dajudaju awa ba awon baba wa lori esin kan. Dajudaju awa si ni olumona lori oripa won
وَكَذَٰلِكَ مَا أَرْسَلْنَا مِنْ قَبْلِكَ فِي قَرْيَةٍ مِنْ نَذِيرٍ إِلَّا قَالَ مُتْرَفُوهَا إِنَّا وَجَدْنَا آبَاءَنَا عَلَىٰ أُمَّةٍ وَإِنَّا عَلَىٰ آثَارِهِمْ مُقْتَدُونَ
Bakan naa, Awa ko ran olukilo kan si ilu kan siwaju re, ayafi ki awon onigbedemuke ilu naa wi pe: "Dajudaju awa ba awon baba wa lori esin kan. Dajudaju awa si ni olutele won lori oripa won

Choose other languages: