Quran Apps in many lanuages:

Surah Az-Zukhruf Ayahs #24 Translated in Yoruba

وَقَالُوا لَوْ شَاءَ الرَّحْمَٰنُ مَا عَبَدْنَاهُمْ ۗ مَا لَهُمْ بِذَٰلِكَ مِنْ عِلْمٍ ۖ إِنْ هُمْ إِلَّا يَخْرُصُونَ
Won tun wi pe: "Ti Ajoke-aye ba fe, awa iba ti josin fun won." Ko si imo kan fun won nipa iyen. Won ko si je kini kan bi ko se pe won n paro
أَمْ آتَيْنَاهُمْ كِتَابًا مِنْ قَبْلِهِ فَهُمْ بِهِ مُسْتَمْسِكُونَ
Tabi A ti fun won ni Tira kan siwaju al-Ƙur’an, ti won n lo ni eri
بَلْ قَالُوا إِنَّا وَجَدْنَا آبَاءَنَا عَلَىٰ أُمَّةٍ وَإِنَّا عَلَىٰ آثَارِهِمْ مُهْتَدُونَ
Rara. Won wi pe: "Dajudaju awa ba awon baba wa lori esin kan. Dajudaju awa si ni olumona lori oripa won
وَكَذَٰلِكَ مَا أَرْسَلْنَا مِنْ قَبْلِكَ فِي قَرْيَةٍ مِنْ نَذِيرٍ إِلَّا قَالَ مُتْرَفُوهَا إِنَّا وَجَدْنَا آبَاءَنَا عَلَىٰ أُمَّةٍ وَإِنَّا عَلَىٰ آثَارِهِمْ مُقْتَدُونَ
Bakan naa, Awa ko ran olukilo kan si ilu kan siwaju re, ayafi ki awon onigbedemuke ilu naa wi pe: "Dajudaju awa ba awon baba wa lori esin kan. Dajudaju awa si ni olutele won lori oripa won
قَالَ أَوَلَوْ جِئْتُكُمْ بِأَهْدَىٰ مِمَّا وَجَدْتُمْ عَلَيْهِ آبَاءَكُمْ ۖ قَالُوا إِنَّا بِمَا أُرْسِلْتُمْ بِهِ كَافِرُونَ
(Olukilo) si so pe: "Nje emi ko ti mu wa fun yin ohun ti o je imona julo si ohun ti e ba awon baba yin lori re?" Won wi pe: "Dajudaju awa je alaigbagbo ninu ohun ti Won fi ran yin nise

Choose other languages: