Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Tawba Ayahs #66 Translated in Yoruba

يَحْلِفُونَ بِاللَّهِ لَكُمْ لِيُرْضُوكُمْ وَاللَّهُ وَرَسُولُهُ أَحَقُّ أَنْ يُرْضُوهُ إِنْ كَانُوا مُؤْمِنِينَ
Won n fi Allahu bura fun yin lati wa iyonu yin. Allahu ati Ojise Re l’o si ye ki won wa iyonu Re ti won ba je onigbagbo ododo
أَلَمْ يَعْلَمُوا أَنَّهُ مَنْ يُحَادِدِ اللَّهَ وَرَسُولَهُ فَأَنَّ لَهُ نَارَ جَهَنَّمَ خَالِدًا فِيهَا ۚ ذَٰلِكَ الْخِزْيُ الْعَظِيمُ
Se won ko mo pe enikeni t’o ba n tako Allahu ati Ojise Re, dajudaju ina Jahanamo ti wa fun un ni? Olusegbere si ni ninu re. Iyen si ni abuku nla
يَحْذَرُ الْمُنَافِقُونَ أَنْ تُنَزَّلَ عَلَيْهِمْ سُورَةٌ تُنَبِّئُهُمْ بِمَا فِي قُلُوبِهِمْ ۚ قُلِ اسْتَهْزِئُوا إِنَّ اللَّهَ مُخْرِجٌ مَا تَحْذَرُونَ
Awon sobe-selu musulumi n beru pe ki A ma se so surah kan kale nipa won, ti o maa fun won ni iro ohun ti n be ninu okan won. So pe: "E maa se yeye lo. Dajudaju Allahu yoo safi han ohun ti e n beru
وَلَئِنْ سَأَلْتَهُمْ لَيَقُولُنَّ إِنَّمَا كُنَّا نَخُوضُ وَنَلْعَبُ ۚ قُلْ أَبِاللَّهِ وَآيَاتِهِ وَرَسُولِهِ كُنْتُمْ تَسْتَهْزِئُونَ
Ti o ba kuku bi won leere, dajudaju won a wi pe: "Awa kan n rojo lasan ni, a si n sawada ni." So pe: "Se Allahu, awon ayah Re ati Ojise Re ni e n fi se yeye
لَا تَعْتَذِرُوا قَدْ كَفَرْتُمْ بَعْدَ إِيمَانِكُمْ ۚ إِنْ نَعْفُ عَنْ طَائِفَةٍ مِنْكُمْ نُعَذِّبْ طَائِفَةً بِأَنَّهُمْ كَانُوا مُجْرِمِينَ
E ma se mu awawi wa. Dajudaju e ti sai gbagbo leyin igbagbo yin. Ti A ba se amojukuro fun apa kan ninu yin, A oo fiya je apa kan nitori pe won je elese

Choose other languages: