Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Tawba Ayahs #58 Translated in Yoruba

وَمَا مَنَعَهُمْ أَنْ تُقْبَلَ مِنْهُمْ نَفَقَاتُهُمْ إِلَّا أَنَّهُمْ كَفَرُوا بِاللَّهِ وَبِرَسُولِهِ وَلَا يَأْتُونَ الصَّلَاةَ إِلَّا وَهُمْ كُسَالَىٰ وَلَا يُنْفِقُونَ إِلَّا وَهُمْ كَارِهُونَ
Ko si si ohun kan ti ko je ki A gba inawo won lowo won bi ko se pe dajudaju won sai gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. Won ko nii wa kirun afi ki won je oroju alainikan-anse. Won ko si nii nawo fesin afi ki emi won ko o
فَلَا تُعْجِبْكَ أَمْوَالُهُمْ وَلَا أَوْلَادُهُمْ ۚ إِنَّمَا يُرِيدُ اللَّهُ لِيُعَذِّبَهُمْ بِهَا فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَتَزْهَقَ أَنْفُسُهُمْ وَهُمْ كَافِرُونَ
Nitori naa, ma se je ki awon dukia won ati awon omo won ya o lenu; Allahu kan fe fi je won niya ninu isemi aye (yii) ni. Emi yo si bo lara won, ti won maa wa nipo alaigbagbo
وَيَحْلِفُونَ بِاللَّهِ إِنَّهُمْ لَمِنْكُمْ وَمَا هُمْ مِنْكُمْ وَلَٰكِنَّهُمْ قَوْمٌ يَفْرَقُونَ
Won n fi Allahu bura pe dajudaju awon kuku wa lara yin. Won ko si si lara yin, sugbon dajudaju won je ijo kan t’o n beru
لَوْ يَجِدُونَ مَلْجَأً أَوْ مَغَارَاتٍ أَوْ مُدَّخَلًا لَوَلَّوْا إِلَيْهِ وَهُمْ يَجْمَحُونَ
Ti o ba je pe won ri ibusasi kan, tabi awon iho apata kan, tabi ibusawo kan, won iba seri sibe ni werewere
وَمِنْهُمْ مَنْ يَلْمِزُكَ فِي الصَّدَقَاتِ فَإِنْ أُعْطُوا مِنْهَا رَضُوا وَإِنْ لَمْ يُعْطَوْا مِنْهَا إِذَا هُمْ يَسْخَطُونَ
O tun wa ninu won, eni ti n da o lebi nibi (pipin) awon ore. Ti A ba fun won ninu re, won a yonu (si i). Ti A o ba si fun won ninu re, nigba naa ni won yoo maa binu

Choose other languages: