Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Talaq Ayahs #11 Translated in Yoruba

لِيُنْفِقْ ذُو سَعَةٍ مِنْ سَعَتِهِ ۖ وَمَنْ قُدِرَ عَلَيْهِ رِزْقُهُ فَلْيُنْفِقْ مِمَّا آتَاهُ اللَّهُ ۚ لَا يُكَلِّفُ اللَّهُ نَفْسًا إِلَّا مَا آتَاهَا ۚ سَيَجْعَلُ اللَّهُ بَعْدَ عُسْرٍ يُسْرًا
Ki oloro na ninu oro re. Eni ti A si diwon arisiki re fun (niwonba), ki o na ninu ohun ti Allahu fun un. Allahu ko labo emi kan lorun ayafi nnkan ti O fun un. Allahu yo si mu irorun wa leyin inira
وَكَأَيِّنْ مِنْ قَرْيَةٍ عَتَتْ عَنْ أَمْرِ رَبِّهَا وَرُسُلِهِ فَحَاسَبْنَاهَا حِسَابًا شَدِيدًا وَعَذَّبْنَاهَا عَذَابًا نُكْرًا
Meloo meloo ninu awon ilu ti won yapa ase Oluwa Re ati awon Ojise Re. A si maa siro ise won ni isiro lile. Ati pe A maa je won niya t’o buru gan-an
فَذَاقَتْ وَبَالَ أَمْرِهَا وَكَانَ عَاقِبَةُ أَمْرِهَا خُسْرًا
Nitori naa, won to iya oran won wo. Ikangun oro won si je ofo
أَعَدَّ اللَّهُ لَهُمْ عَذَابًا شَدِيدًا ۖ فَاتَّقُوا اللَّهَ يَا أُولِي الْأَلْبَابِ الَّذِينَ آمَنُوا ۚ قَدْ أَنْزَلَ اللَّهُ إِلَيْكُمْ ذِكْرًا
Allahu ti pese iya lile sile de won. Nitori naa, e beru Allahu, eyin onilaakaye ti e gbagbo ni ododo. Allahu kuku ti so iranti kale fun yin
رَسُولًا يَتْلُو عَلَيْكُمْ آيَاتِ اللَّهِ مُبَيِّنَاتٍ لِيُخْرِجَ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ مِنَ الظُّلُمَاتِ إِلَى النُّورِ ۚ وَمَنْ يُؤْمِنْ بِاللَّهِ وَيَعْمَلْ صَالِحًا يُدْخِلْهُ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا أَبَدًا ۖ قَدْ أَحْسَنَ اللَّهُ لَهُ رِزْقًا
Ojise kan ti o maa ke awon ayah Allahu t’o yanju fun yin nitori ki o le mu awon t’o gbagbo ni ododo, ti won tun se awon ise rere, kuro ninu awon okunkun lo sinu imole. Enikeni ti o ba gba Allahu gbo ni ododo, ti o si n se ise rere, O maa mu un wo inu awon Ogba Idera, ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re titi laelae. Dajudaju Allahu ti se arisiki t’o dara julo fun un

Choose other languages: