Quran Apps in many lanuages:

Surah Ar-Rum Ayahs #28 Translated in Yoruba

وَمِنْ آيَاتِهِ يُرِيكُمُ الْبَرْقَ خَوْفًا وَطَمَعًا وَيُنَزِّلُ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَيُحْيِي بِهِ الْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَعْقِلُونَ
Ninu awon ami Re tun ni fifi monamona han yin ni ti eru ati ireti. O si n so omi kale lati sanmo. O n fi ta ile ji leyin ti ile ti ku. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o n se laakaye
وَمِنْ آيَاتِهِ أَنْ تَقُومَ السَّمَاءُ وَالْأَرْضُ بِأَمْرِهِ ۚ ثُمَّ إِذَا دَعَاكُمْ دَعْوَةً مِنَ الْأَرْضِ إِذَا أَنْتُمْ تَخْرُجُونَ
Ati pe ninu awon ami Re ni pe sanmo ati ile duro pelu ase Re. Leyin naa, nigba ti O ba pe yin ni ipe kan nigba naa ni eyin yoo maa jade lati inu ile
وَلَهُ مَنْ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ كُلٌّ لَهُ قَانِتُونَ
TiRe ni awon t’o wa ninu awon sanmo ati ile. Eni kookan ni olutele-ase Re
وَهُوَ الَّذِي يَبْدَأُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ وَهُوَ أَهْوَنُ عَلَيْهِ ۚ وَلَهُ الْمَثَلُ الْأَعْلَىٰ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Oun ni Eni ti O n bere eda dida. Leyin naa, O maa da a pada (sipo alaaye fun ajinde). O si rorun julo fun Un (lati se bee). TiRe ni iroyin t’o ga julo ninu awon sanmo ati ile. Oun si ni Alagbara, Ologbon
ضَرَبَ لَكُمْ مَثَلًا مِنْ أَنْفُسِكُمْ ۖ هَلْ لَكُمْ مِنْ مَا مَلَكَتْ أَيْمَانُكُمْ مِنْ شُرَكَاءَ فِي مَا رَزَقْنَاكُمْ فَأَنْتُمْ فِيهِ سَوَاءٌ تَخَافُونَهُمْ كَخِيفَتِكُمْ أَنْفُسَكُمْ ۚ كَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ الْآيَاتِ لِقَوْمٍ يَعْقِلُونَ
(Allahu) sakawe kan fun yin nipa ara yin. Nje e ni akegbe ninu awon eru yin lori ohun ti A fun yin ni arisiki, ti e jo maa pin (dukia naa) ni dogbadogba, ti e o si maa paya won gege bi won se n paya eyin naa? Bayen ni A se n s’alaye awon ayah fun ijo t’o n se laakaye

Choose other languages: