Quran Apps in many lanuages:

Surah Ar-Rum Ayahs #31 Translated in Yoruba

وَهُوَ الَّذِي يَبْدَأُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ وَهُوَ أَهْوَنُ عَلَيْهِ ۚ وَلَهُ الْمَثَلُ الْأَعْلَىٰ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Oun ni Eni ti O n bere eda dida. Leyin naa, O maa da a pada (sipo alaaye fun ajinde). O si rorun julo fun Un (lati se bee). TiRe ni iroyin t’o ga julo ninu awon sanmo ati ile. Oun si ni Alagbara, Ologbon
ضَرَبَ لَكُمْ مَثَلًا مِنْ أَنْفُسِكُمْ ۖ هَلْ لَكُمْ مِنْ مَا مَلَكَتْ أَيْمَانُكُمْ مِنْ شُرَكَاءَ فِي مَا رَزَقْنَاكُمْ فَأَنْتُمْ فِيهِ سَوَاءٌ تَخَافُونَهُمْ كَخِيفَتِكُمْ أَنْفُسَكُمْ ۚ كَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ الْآيَاتِ لِقَوْمٍ يَعْقِلُونَ
(Allahu) sakawe kan fun yin nipa ara yin. Nje e ni akegbe ninu awon eru yin lori ohun ti A fun yin ni arisiki, ti e jo maa pin (dukia naa) ni dogbadogba, ti e o si maa paya won gege bi won se n paya eyin naa? Bayen ni A se n s’alaye awon ayah fun ijo t’o n se laakaye
بَلِ اتَّبَعَ الَّذِينَ ظَلَمُوا أَهْوَاءَهُمْ بِغَيْرِ عِلْمٍ ۖ فَمَنْ يَهْدِي مَنْ أَضَلَّ اللَّهُ ۖ وَمَا لَهُمْ مِنْ نَاصِرِينَ
Nse ni awon t’o sabosi tele ife-inu won lai si imo kan (fun won). Ta si ni o le fi ona mo eni ti Allahu ba si lona? Ko si nii si awon alaranse fun won
فَأَقِمْ وَجْهَكَ لِلدِّينِ حَنِيفًا ۚ فِطْرَتَ اللَّهِ الَّتِي فَطَرَ النَّاسَ عَلَيْهَا ۚ لَا تَبْدِيلَ لِخَلْقِ اللَّهِ ۚ ذَٰلِكَ الدِّينُ الْقَيِّمُ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ
Nitori naa, doju re ko esin naa, (ki o je) oluduro-deede-ninu-esin, esin adamo Allahu eyi ti O da mo awon eniyan. Ko si si iyipada fun eda Allahu. Iyen ni esin t’o feserinle, sugbon opolopo awon eniyan ko mo
مُنِيبِينَ إِلَيْهِ وَاتَّقُوهُ وَأَقِيمُوا الصَّلَاةَ وَلَا تَكُونُوا مِنَ الْمُشْرِكِينَ
(E je) oluseri si odo Allahu (nipa ironupiwada). E paya Re. E kirun. E ma se wa ninu awon osebo

Choose other languages: