Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nur Ayahs #19 Translated in Yoruba

إِذْ تَلَقَّوْنَهُ بِأَلْسِنَتِكُمْ وَتَقُولُونَ بِأَفْوَاهِكُمْ مَا لَيْسَ لَكُمْ بِهِ عِلْمٌ وَتَحْسَبُونَهُ هَيِّنًا وَهُوَ عِنْدَ اللَّهِ عَظِيمٌ
(E ranti) nigba ti e n gba a (laaarin ara yin) pelu ahon yin, ti e si n fi enu yin so ohun ti e o nimo nipa re; e lero pe nnkan t’o fuye ni, nnkan nla si ni lodo Allahu
وَلَوْلَا إِذْ سَمِعْتُمُوهُ قُلْتُمْ مَا يَكُونُ لَنَا أَنْ نَتَكَلَّمَ بِهَٰذَا سُبْحَانَكَ هَٰذَا بُهْتَانٌ عَظِيمٌ
Nigba ti e gbo o, ki ni ko je ki e so pe: “Ki i se eto fun wa pe ki a so eyi. Mimo ni fun O (Allahu)! Eyi ni iparo-moni t’o tobi.”
يَعِظُكُمُ اللَّهُ أَنْ تَعُودُوا لِمِثْلِهِ أَبَدًا إِنْ كُنْتُمْ مُؤْمِنِينَ
Allahu n se waasi fun yin pe ki e ma se pada sibi iru re mo laelae ti e ba je onigbagbo ododo
وَيُبَيِّنُ اللَّهُ لَكُمُ الْآيَاتِ ۚ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
Allahu n salaye awon ayah naa. Allahu si ni Onimo, Ologbon
إِنَّ الَّذِينَ يُحِبُّونَ أَنْ تَشِيعَ الْفَاحِشَةُ فِي الَّذِينَ آمَنُوا لَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ ۚ وَاللَّهُ يَعْلَمُ وَأَنْتُمْ لَا تَعْلَمُونَ
Dajudaju awon t’o nifee si ki (oro) ibaje maa tan kale nipa awon t’o gbagbo ni ododo, iya eleta-elero n be fun won ni aye ati ni orun. Allahu nimo, eyin ko si nimo

Choose other languages: