Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nur Ayahs #18 Translated in Yoruba

وَلَوْلَا فَضْلُ اللَّهِ عَلَيْكُمْ وَرَحْمَتُهُ فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ لَمَسَّكُمْ فِي مَا أَفَضْتُمْ فِيهِ عَذَابٌ عَظِيمٌ
Ti ki i ba se ti oore ajulo Allahu ati ike Re lori yin ni ile aye ati ni orun ni, dajudaju iya nla iba fowo ba yin nipa ohun ti e n so kiri ni isokuso
إِذْ تَلَقَّوْنَهُ بِأَلْسِنَتِكُمْ وَتَقُولُونَ بِأَفْوَاهِكُمْ مَا لَيْسَ لَكُمْ بِهِ عِلْمٌ وَتَحْسَبُونَهُ هَيِّنًا وَهُوَ عِنْدَ اللَّهِ عَظِيمٌ
(E ranti) nigba ti e n gba a (laaarin ara yin) pelu ahon yin, ti e si n fi enu yin so ohun ti e o nimo nipa re; e lero pe nnkan t’o fuye ni, nnkan nla si ni lodo Allahu
وَلَوْلَا إِذْ سَمِعْتُمُوهُ قُلْتُمْ مَا يَكُونُ لَنَا أَنْ نَتَكَلَّمَ بِهَٰذَا سُبْحَانَكَ هَٰذَا بُهْتَانٌ عَظِيمٌ
Nigba ti e gbo o, ki ni ko je ki e so pe: “Ki i se eto fun wa pe ki a so eyi. Mimo ni fun O (Allahu)! Eyi ni iparo-moni t’o tobi.”
يَعِظُكُمُ اللَّهُ أَنْ تَعُودُوا لِمِثْلِهِ أَبَدًا إِنْ كُنْتُمْ مُؤْمِنِينَ
Allahu n se waasi fun yin pe ki e ma se pada sibi iru re mo laelae ti e ba je onigbagbo ododo
وَيُبَيِّنُ اللَّهُ لَكُمُ الْآيَاتِ ۚ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
Allahu n salaye awon ayah naa. Allahu si ni Onimo, Ologbon

Choose other languages: