Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #102 Translated in Yoruba

إِلَّا الْمُسْتَضْعَفِينَ مِنَ الرِّجَالِ وَالنِّسَاءِ وَالْوِلْدَانِ لَا يَسْتَطِيعُونَ حِيلَةً وَلَا يَهْتَدُونَ سَبِيلًا
Ayafi awon alailagbara ninu awon okunrin, awon obinrin ati awon omode ti ko ni ikapa ogbon kan, ti won ko si da ona mo (de ilu Modinah)
فَأُولَٰئِكَ عَسَى اللَّهُ أَنْ يَعْفُوَ عَنْهُمْ ۚ وَكَانَ اللَّهُ عَفُوًّا غَفُورًا
Nitori naa, awon wonyen, o sunmo ki Allahu samojukuro fun won. Allahu si n je Alamojuukuro, Alaforijin
وَمَنْ يُهَاجِرْ فِي سَبِيلِ اللَّهِ يَجِدْ فِي الْأَرْضِ مُرَاغَمًا كَثِيرًا وَسَعَةً ۚ وَمَنْ يَخْرُجْ مِنْ بَيْتِهِ مُهَاجِرًا إِلَى اللَّهِ وَرَسُولِهِ ثُمَّ يُدْرِكْهُ الْمَوْتُ فَقَدْ وَقَعَ أَجْرُهُ عَلَى اللَّهِ ۗ وَكَانَ اللَّهُ غَفُورًا رَحِيمًا
Enikeni ti o ba gbe ilu re ju sile nitori esin Allahu, o maa ri opolopo ibusasi ati igbalaaye lori ile. Enikeni ti o ba jade kuro ninu ile re (ti o je) olufilu-sile nitori esin Allahu ati Ojise Re, leyin naa ti iku ba a (loju ona), esan re kuku ti wa lodo Allahu. Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun
وَإِذَا ضَرَبْتُمْ فِي الْأَرْضِ فَلَيْسَ عَلَيْكُمْ جُنَاحٌ أَنْ تَقْصُرُوا مِنَ الصَّلَاةِ إِنْ خِفْتُمْ أَنْ يَفْتِنَكُمُ الَّذِينَ كَفَرُوا ۚ إِنَّ الْكَافِرِينَ كَانُوا لَكُمْ عَدُوًّا مُبِينًا
Nigba ti e ba se irin-ajo lori ile, ko si ese fun yin lati din irun ku, ti eyin ba n beru pe awon t’o sai gbagbo yoo fooro yin. Dajudaju awon alaigbagbo, won je ota ponnbele fun yin
وَإِذَا كُنْتَ فِيهِمْ فَأَقَمْتَ لَهُمُ الصَّلَاةَ فَلْتَقُمْ طَائِفَةٌ مِنْهُمْ مَعَكَ وَلْيَأْخُذُوا أَسْلِحَتَهُمْ فَإِذَا سَجَدُوا فَلْيَكُونُوا مِنْ وَرَائِكُمْ وَلْتَأْتِ طَائِفَةٌ أُخْرَىٰ لَمْ يُصَلُّوا فَلْيُصَلُّوا مَعَكَ وَلْيَأْخُذُوا حِذْرَهُمْ وَأَسْلِحَتَهُمْ ۗ وَدَّ الَّذِينَ كَفَرُوا لَوْ تَغْفُلُونَ عَنْ أَسْلِحَتِكُمْ وَأَمْتِعَتِكُمْ فَيَمِيلُونَ عَلَيْكُمْ مَيْلَةً وَاحِدَةً ۚ وَلَا جُنَاحَ عَلَيْكُمْ إِنْ كَانَ بِكُمْ أَذًى مِنْ مَطَرٍ أَوْ كُنْتُمْ مَرْضَىٰ أَنْ تَضَعُوا أَسْلِحَتَكُمْ ۖ وَخُذُوا حِذْرَكُمْ ۗ إِنَّ اللَّهَ أَعَدَّ لِلْكَافِرِينَ عَذَابًا مُهِينًا
Nigba ti o ba wa laaarin won, gbe irun duro fun won. Ki igun kan ninu won kirun pelu re, ki won mu nnkan ijagun won lowo. Nigba ti won ba si fori kanle (ti won pari irun), ki won bo seyin yin, ki igun miiran ti ko ti i kirun wa kirun pelu re. Ki won mu isora won ati nnkan ijagun won lowo. Awon t’o sai gbagbo fe ki e gbagbe awon nnkan ijagun yin ati nnkan igbadun yin, ki won le kolu yin ni ee kan naa. Ko si ese fun yin ti o ba je pe ipalara kan n be fun yin latara ojo tabi (pe) e je alaisan, pe ki e fi nnkan ijagun yin sile (lori irun). E mu nnkan isora yin lowo. Dajudaju Allahu ti pese iya ti i yepere eda sile de awon alaigbagbo

Choose other languages: