Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #68 Translated in Yoruba

وَمَا أَرْسَلْنَا مِنْ رَسُولٍ إِلَّا لِيُطَاعَ بِإِذْنِ اللَّهِ ۚ وَلَوْ أَنَّهُمْ إِذْ ظَلَمُوا أَنْفُسَهُمْ جَاءُوكَ فَاسْتَغْفَرُوا اللَّهَ وَاسْتَغْفَرَ لَهُمُ الرَّسُولُ لَوَجَدُوا اللَّهَ تَوَّابًا رَحِيمًا
A o ran Ojise kan nise afi nitori ki won le tele e pelu iyonda Allahu. Ti o ba je pe nigba ti won sabosi si emi ara won, won wa ba o, won si toro aforijin Allahu, ti Ojise si tun ba won toro aforijin, won iba kuku ri Allahu ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun
فَلَا وَرَبِّكَ لَا يُؤْمِنُونَ حَتَّىٰ يُحَكِّمُوكَ فِيمَا شَجَرَ بَيْنَهُمْ ثُمَّ لَا يَجِدُوا فِي أَنْفُسِهِمْ حَرَجًا مِمَّا قَضَيْتَ وَيُسَلِّمُوا تَسْلِيمًا
Rara, Emi fi Oluwa re bura pe won ko ti i gbagbo ni ododo titi won yoo fi gba o ni oludajo lori ohun ti o ba da yanponyanrin sile laaarin won. Leyin naa, won ko nii ni ehonu kan si idajo ti o ba da. Won si maa gba patapata
وَلَوْ أَنَّا كَتَبْنَا عَلَيْهِمْ أَنِ اقْتُلُوا أَنْفُسَكُمْ أَوِ اخْرُجُوا مِنْ دِيَارِكُمْ مَا فَعَلُوهُ إِلَّا قَلِيلٌ مِنْهُمْ ۖ وَلَوْ أَنَّهُمْ فَعَلُوا مَا يُوعَظُونَ بِهِ لَكَانَ خَيْرًا لَهُمْ وَأَشَدَّ تَثْبِيتًا
Ti o ba je pe A se e ni oran-anyan fun won pe: "E para yin tabi e jade kuro ninu ilu yin," won ko nii se e afi die ninu won. Ti o ba tun je pe won se ohun ti A fi n se waasi fun won ni, iba je oore ati idurosinsin to lagbara julo fun won
وَإِذًا لَآتَيْنَاهُمْ مِنْ لَدُنَّا أَجْرًا عَظِيمًا
Nigba naa, dajudaju Awa iba fun won ni esan nla lati odo Wa
وَلَهَدَيْنَاهُمْ صِرَاطًا مُسْتَقِيمًا
Ati pe dajudaju Awa iba to won si ona taara

Choose other languages: