Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #34 Translated in Yoruba

وَمَنْ يَفْعَلْ ذَٰلِكَ عُدْوَانًا وَظُلْمًا فَسَوْفَ نُصْلِيهِ نَارًا ۚ وَكَانَ ذَٰلِكَ عَلَى اللَّهِ يَسِيرًا
Enikeni ti o ba si se iyen lati fi tayo enu-ala ati lati fi se abosi, laipe A maa mu un wo inu Ina. Irorun si ni iyen je fun Allahu
إِنْ تَجْتَنِبُوا كَبَائِرَ مَا تُنْهَوْنَ عَنْهُ نُكَفِّرْ عَنْكُمْ سَيِّئَاتِكُمْ وَنُدْخِلْكُمْ مُدْخَلًا كَرِيمًا
Ti e ba jinna si awon ese nlanla ti A ko fun yin, A maa pa awon iwa aidaa yin re fun yin, A si maa mu yin wo aye alapon-onle
وَلَا تَتَمَنَّوْا مَا فَضَّلَ اللَّهُ بِهِ بَعْضَكُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ ۚ لِلرِّجَالِ نَصِيبٌ مِمَّا اكْتَسَبُوا ۖ وَلِلنِّسَاءِ نَصِيبٌ مِمَّا اكْتَسَبْنَ ۚ وَاسْأَلُوا اللَّهَ مِنْ فَضْلِهِ ۗ إِنَّ اللَّهَ كَانَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمًا
E ma se jerankan ohun ti Allahu fi s’oore ajulo fun apa kan yin lori apa kan. Ipin (esan) n be fun awon okunrin nipa ohun ti won se nise, ipin (esan) si n be fun awon obinrin nipa ohun ti won se nise. Ki e si toro lodo Allahu alekun oore Re. Dajudaju Allahu n je Onimo nipa gbogbo nnkan
وَلِكُلٍّ جَعَلْنَا مَوَالِيَ مِمَّا تَرَكَ الْوَالِدَانِ وَالْأَقْرَبُونَ ۚ وَالَّذِينَ عَقَدَتْ أَيْمَانُكُمْ فَآتُوهُمْ نَصِيبَهُمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ كَانَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ شَهِيدًا
Ikookan (awon dukia) ni A ti se adayanri re fun awon ti o maa jogun re ninu ohun ti awon obi ati ebi fi sile. Awon ti e si bura fun (pe e maa fun ni nnkan), e fun won ni ipin won. Dajudaju Allahu n je Elerii lori gbogbo nnkan
الرِّجَالُ قَوَّامُونَ عَلَى النِّسَاءِ بِمَا فَضَّلَ اللَّهُ بَعْضَهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ وَبِمَا أَنْفَقُوا مِنْ أَمْوَالِهِمْ ۚ فَالصَّالِحَاتُ قَانِتَاتٌ حَافِظَاتٌ لِلْغَيْبِ بِمَا حَفِظَ اللَّهُ ۚ وَاللَّاتِي تَخَافُونَ نُشُوزَهُنَّ فَعِظُوهُنَّ وَاهْجُرُوهُنَّ فِي الْمَضَاجِعِ وَاضْرِبُوهُنَّ ۖ فَإِنْ أَطَعْنَكُمْ فَلَا تَبْغُوا عَلَيْهِنَّ سَبِيلًا ۗ إِنَّ اللَّهَ كَانَ عَلِيًّا كَبِيرًا
Awon okunrin ni opomulero (alase) fun awon obinrin nitori pe Allahu s’oore ajulo fun apa kan won lori apa kan ati nitori ohun ti won n na ninu dukia won. Awon obinrin rere ni awon olutele-ase (Allahu ati ase oko), awon oluso-eto oko ni koro fun wi pe Allahu so (eto tiwon naa fun won lodo oko won). Awon ti e si n paya orikunkun won, e se waasi fun won, e takete si ibusun won, e lu won. Ti won ba si tele ase yin, e ma se fi ona kan wa won nija. Dajudaju Allahu ga, O tobi

Choose other languages: