Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #37 Translated in Yoruba

وَلِكُلٍّ جَعَلْنَا مَوَالِيَ مِمَّا تَرَكَ الْوَالِدَانِ وَالْأَقْرَبُونَ ۚ وَالَّذِينَ عَقَدَتْ أَيْمَانُكُمْ فَآتُوهُمْ نَصِيبَهُمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ كَانَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ شَهِيدًا
Ikookan (awon dukia) ni A ti se adayanri re fun awon ti o maa jogun re ninu ohun ti awon obi ati ebi fi sile. Awon ti e si bura fun (pe e maa fun ni nnkan), e fun won ni ipin won. Dajudaju Allahu n je Elerii lori gbogbo nnkan
الرِّجَالُ قَوَّامُونَ عَلَى النِّسَاءِ بِمَا فَضَّلَ اللَّهُ بَعْضَهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ وَبِمَا أَنْفَقُوا مِنْ أَمْوَالِهِمْ ۚ فَالصَّالِحَاتُ قَانِتَاتٌ حَافِظَاتٌ لِلْغَيْبِ بِمَا حَفِظَ اللَّهُ ۚ وَاللَّاتِي تَخَافُونَ نُشُوزَهُنَّ فَعِظُوهُنَّ وَاهْجُرُوهُنَّ فِي الْمَضَاجِعِ وَاضْرِبُوهُنَّ ۖ فَإِنْ أَطَعْنَكُمْ فَلَا تَبْغُوا عَلَيْهِنَّ سَبِيلًا ۗ إِنَّ اللَّهَ كَانَ عَلِيًّا كَبِيرًا
Awon okunrin ni opomulero (alase) fun awon obinrin nitori pe Allahu s’oore ajulo fun apa kan won lori apa kan ati nitori ohun ti won n na ninu dukia won. Awon obinrin rere ni awon olutele-ase (Allahu ati ase oko), awon oluso-eto oko ni koro fun wi pe Allahu so (eto tiwon naa fun won lodo oko won). Awon ti e si n paya orikunkun won, e se waasi fun won, e takete si ibusun won, e lu won. Ti won ba si tele ase yin, e ma se fi ona kan wa won nija. Dajudaju Allahu ga, O tobi
وَإِنْ خِفْتُمْ شِقَاقَ بَيْنِهِمَا فَابْعَثُوا حَكَمًا مِنْ أَهْلِهِ وَحَكَمًا مِنْ أَهْلِهَا إِنْ يُرِيدَا إِصْلَاحًا يُوَفِّقِ اللَّهُ بَيْنَهُمَا ۗ إِنَّ اللَّهَ كَانَ عَلِيمًا خَبِيرًا
Ti e ba si mo pe iyapa wa laaarin awon mejeeji, e gbe oloye kan dide lati inu ebi oko ati oloye kan lati inu ebi iyawo. Ti awon (toko tiyawo) mejeeji ba n fe atunse, Allahu yoo fi awon (oloye mejeeji) se konge atunse lori oro aarin won. Dajudaju Allahu n je Onimo, Alamotan
وَاعْبُدُوا اللَّهَ وَلَا تُشْرِكُوا بِهِ شَيْئًا ۖ وَبِالْوَالِدَيْنِ إِحْسَانًا وَبِذِي الْقُرْبَىٰ وَالْيَتَامَىٰ وَالْمَسَاكِينِ وَالْجَارِ ذِي الْقُرْبَىٰ وَالْجَارِ الْجُنُبِ وَالصَّاحِبِ بِالْجَنْبِ وَابْنِ السَّبِيلِ وَمَا مَلَكَتْ أَيْمَانُكُمْ ۗ إِنَّ اللَّهَ لَا يُحِبُّ مَنْ كَانَ مُخْتَالًا فَخُورًا
E josin fun Allahu, e ma se fi nnkan kan sebo si I. E se daadaa si awon obi mejeeji ati ebi ati awon omo orukan ati awon mekunnu ati aladuugbo t’o sunmo ati aladuugbo t’o jinna ati ore alabaarin ati eni ti agara da lori irin-ajo ati awon eru yin. Dajudaju Allahu ko nifee onigbeeraga, afonnu
الَّذِينَ يَبْخَلُونَ وَيَأْمُرُونَ النَّاسَ بِالْبُخْلِ وَيَكْتُمُونَ مَا آتَاهُمُ اللَّهُ مِنْ فَضْلِهِ ۗ وَأَعْتَدْنَا لِلْكَافِرِينَ عَذَابًا مُهِينًا
Awon t’o n sahun, (awon) t’o n pa eniyan lase ahun sise ati (awon) t’o n fi ohun ti Allahu fun won ninu oore ajulo Re pamo; A ti pese iya ti i yepere eda sile de awon alaigbagbo

Choose other languages: