Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #170 Translated in Yoruba

لَٰكِنِ اللَّهُ يَشْهَدُ بِمَا أَنْزَلَ إِلَيْكَ ۖ أَنْزَلَهُ بِعِلْمِهِ ۖ وَالْمَلَائِكَةُ يَشْهَدُونَ ۚ وَكَفَىٰ بِاللَّهِ شَهِيدًا
Sugbon Allahu n jerii si ohun ti O sokale fun o. O so o kale pelu imo Re. Awon molaika naa n jerii (si i). Allahu si to ni Elerii
إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا وَصَدُّوا عَنْ سَبِيلِ اللَّهِ قَدْ ضَلُّوا ضَلَالًا بَعِيدًا
Dajudaju awon t’o sai gbagbo, ti won si seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, won kuku ti sina ni isina t’o jinna
إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا وَظَلَمُوا لَمْ يَكُنِ اللَّهُ لِيَغْفِرَ لَهُمْ وَلَا لِيَهْدِيَهُمْ طَرِيقًا
Dajudaju awon t’o sai gbagbo, ti won tun sabosi, Allahu ko nii fori jin won, ko si nii fi oju-ona mo won
إِلَّا طَرِيقَ جَهَنَّمَ خَالِدِينَ فِيهَا أَبَدًا ۚ وَكَانَ ذَٰلِكَ عَلَى اللَّهِ يَسِيرًا
Ayafi oju-ona ina Jahanamo. Olusegbere ni won ninu re titi laelae. Iyen si n je irorun fun Allahu
يَا أَيُّهَا النَّاسُ قَدْ جَاءَكُمُ الرَّسُولُ بِالْحَقِّ مِنْ رَبِّكُمْ فَآمِنُوا خَيْرًا لَكُمْ ۚ وَإِنْ تَكْفُرُوا فَإِنَّ لِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ وَكَانَ اللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمًا
Eyin eniyan, dajudaju Ojise naa ti de ba yin pelu ododo lati odo Oluwa yin. Nitori naa, ki e gba a gbo l’o dara julo fun yin. Ti e ba si sai gbagbo, dajudaju ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. Allahu si n je Onimo, Ologbon

Choose other languages: