Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #158 Translated in Yoruba

وَرَفَعْنَا فَوْقَهُمُ الطُّورَ بِمِيثَاقِهِمْ وَقُلْنَا لَهُمُ ادْخُلُوا الْبَابَ سُجَّدًا وَقُلْنَا لَهُمْ لَا تَعْدُوا فِي السَّبْتِ وَأَخَذْنَا مِنْهُمْ مِيثَاقًا غَلِيظًا
A gbe apata soke ori won nitori majemu won. A si so fun won pe: “E gba enu-ona ilu wole ni oluteriba.” A tun so fun won pe: “E ma se tayo enu-ala ni ojo Sabt.” A si gba adehun t’o nipon lowo won
فَبِمَا نَقْضِهِمْ مِيثَاقَهُمْ وَكُفْرِهِمْ بِآيَاتِ اللَّهِ وَقَتْلِهِمُ الْأَنْبِيَاءَ بِغَيْرِ حَقٍّ وَقَوْلِهِمْ قُلُوبُنَا غُلْفٌ ۚ بَلْ طَبَعَ اللَّهُ عَلَيْهَا بِكُفْرِهِمْ فَلَا يُؤْمِنُونَ إِلَّا قَلِيلًا
Nitori yiye ti won funra won ye adehun won, sisaigbagbo won ninu awon oro Allahu, pipa ti won n pa awon Anabi lai letoo ati wiwi ti won n wi pe: “Okan wa ti di.” – rara, Allahu ti fi edidi di okan won ni nitori aigbagbo won. – Nitori naa, won ko nii gbagbo afi die (ninu won)
وَبِكُفْرِهِمْ وَقَوْلِهِمْ عَلَىٰ مَرْيَمَ بُهْتَانًا عَظِيمًا
Ati nitori aigbagbo won ati oro won lori Moryam ni ti ibanilorukoje t’o tobi (Allahu tun fi edidi di okan won)
وَقَوْلِهِمْ إِنَّا قَتَلْنَا الْمَسِيحَ عِيسَى ابْنَ مَرْيَمَ رَسُولَ اللَّهِ وَمَا قَتَلُوهُ وَمَا صَلَبُوهُ وَلَٰكِنْ شُبِّهَ لَهُمْ ۚ وَإِنَّ الَّذِينَ اخْتَلَفُوا فِيهِ لَفِي شَكٍّ مِنْهُ ۚ مَا لَهُمْ بِهِ مِنْ عِلْمٍ إِلَّا اتِّبَاعَ الظَّنِّ ۚ وَمَا قَتَلُوهُ يَقِينًا
Ati nitori oro won (yii): “Dajudaju awa pa Mosih, ‘Isa omo Moryam, Ojise Allahu.” Won ko pa a, won ko si kan an mo agbelebuu, sugbon A gbe aworan re wo elomiiran fun won ni. Dajudaju awon t’o yapa-enu nipa re, kuku wa ninu iyemeji ninu re; ko si imo kan fun won nipa re afi titele erokero. Won ko pa a ni amodaju. surah ali ‘Imron; 3:7 surah al-’Ani‘am; 6: 99 ati
بَلْ رَفَعَهُ اللَّهُ إِلَيْهِ ۚ وَكَانَ اللَّهُ عَزِيزًا حَكِيمًا
Rara o, Allahu gbe e wa soke lodo Re ni. Allahu si n je Alagbara, Ologbon

Choose other languages: