Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #137 Translated in Yoruba

إِنْ يَشَأْ يُذْهِبْكُمْ أَيُّهَا النَّاسُ وَيَأْتِ بِآخَرِينَ ۚ وَكَانَ اللَّهُ عَلَىٰ ذَٰلِكَ قَدِيرًا
Ti (Allahu) ba fe, O maa ko yin kuro lori ile, eyin eniyan. O si maa mu awon miiran wa. Allahu si n je Alagbara lori iyen
مَنْ كَانَ يُرِيدُ ثَوَابَ الدُّنْيَا فَعِنْدَ اللَّهِ ثَوَابُ الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ ۚ وَكَانَ اللَّهُ سَمِيعًا بَصِيرًا
Enikeni ti o ba n fe esan nile aye, sebi lodo Allahu ni esan aye ati orun wa. Allahu si n je Olugbo, Oluriran
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا كُونُوا قَوَّامِينَ بِالْقِسْطِ شُهَدَاءَ لِلَّهِ وَلَوْ عَلَىٰ أَنْفُسِكُمْ أَوِ الْوَالِدَيْنِ وَالْأَقْرَبِينَ ۚ إِنْ يَكُنْ غَنِيًّا أَوْ فَقِيرًا فَاللَّهُ أَوْلَىٰ بِهِمَا ۖ فَلَا تَتَّبِعُوا الْهَوَىٰ أَنْ تَعْدِلُوا ۚ وَإِنْ تَلْوُوا أَوْ تُعْرِضُوا فَإِنَّ اللَّهَ كَانَ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرًا
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e je oluduro sinsin lori ododo nigba ti e ba n jerii nitori ti Allahu, koda ki (eri jije naa) tako eyin funra yin tabi awon obi mejeeji ati awon ebi; yala o je oloro tabi alaini. Allahu sunmo (yin) ju awon mejeeji lo. Nitori naa, e ma se tele ife-inu lati ma se deede. Ti e ba yi oju-oro sodi tabi ti e ba gbunri kuro (nibi deede), dajudaju Allahu n je Alamotan nipa ohun ti e n se nise
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا آمِنُوا بِاللَّهِ وَرَسُولِهِ وَالْكِتَابِ الَّذِي نَزَّلَ عَلَىٰ رَسُولِهِ وَالْكِتَابِ الَّذِي أَنْزَلَ مِنْ قَبْلُ ۚ وَمَنْ يَكْفُرْ بِاللَّهِ وَمَلَائِكَتِهِ وَكُتُبِهِ وَرُسُلِهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ فَقَدْ ضَلَّ ضَلَالًا بَعِيدًا
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e gbagbo daadaa ninu Allahu ati Ojise Re, ati Tira ti (Allahu) sokale fun Ojise Re, ati Tira ti O sokale siwaju. Enikeni ti o ba sai gbagbo ninu Allahu, awon molaika Re, awon Tira Re, awon Ojise Re ati Ojo Ikeyin, dajudaju o ti sina ni isina t’o jinna tefetefe
إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا ثُمَّ كَفَرُوا ثُمَّ آمَنُوا ثُمَّ كَفَرُوا ثُمَّ ازْدَادُوا كُفْرًا لَمْ يَكُنِ اللَّهُ لِيَغْفِرَ لَهُمْ وَلَا لِيَهْدِيَهُمْ سَبِيلًا
Dajudaju awon t’o gbagbo, leyin naa won sai gbagbo, leyin naa won gbagbo, leyin naa won sai gbagbo, leyin naa won si lekun si i ninu aigbagbo, Allahu ko nii fori jin won, ko si nii fi ona mo won

Choose other languages: