Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #139 Translated in Yoruba

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا كُونُوا قَوَّامِينَ بِالْقِسْطِ شُهَدَاءَ لِلَّهِ وَلَوْ عَلَىٰ أَنْفُسِكُمْ أَوِ الْوَالِدَيْنِ وَالْأَقْرَبِينَ ۚ إِنْ يَكُنْ غَنِيًّا أَوْ فَقِيرًا فَاللَّهُ أَوْلَىٰ بِهِمَا ۖ فَلَا تَتَّبِعُوا الْهَوَىٰ أَنْ تَعْدِلُوا ۚ وَإِنْ تَلْوُوا أَوْ تُعْرِضُوا فَإِنَّ اللَّهَ كَانَ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرًا
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e je oluduro sinsin lori ododo nigba ti e ba n jerii nitori ti Allahu, koda ki (eri jije naa) tako eyin funra yin tabi awon obi mejeeji ati awon ebi; yala o je oloro tabi alaini. Allahu sunmo (yin) ju awon mejeeji lo. Nitori naa, e ma se tele ife-inu lati ma se deede. Ti e ba yi oju-oro sodi tabi ti e ba gbunri kuro (nibi deede), dajudaju Allahu n je Alamotan nipa ohun ti e n se nise
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا آمِنُوا بِاللَّهِ وَرَسُولِهِ وَالْكِتَابِ الَّذِي نَزَّلَ عَلَىٰ رَسُولِهِ وَالْكِتَابِ الَّذِي أَنْزَلَ مِنْ قَبْلُ ۚ وَمَنْ يَكْفُرْ بِاللَّهِ وَمَلَائِكَتِهِ وَكُتُبِهِ وَرُسُلِهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ فَقَدْ ضَلَّ ضَلَالًا بَعِيدًا
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e gbagbo daadaa ninu Allahu ati Ojise Re, ati Tira ti (Allahu) sokale fun Ojise Re, ati Tira ti O sokale siwaju. Enikeni ti o ba sai gbagbo ninu Allahu, awon molaika Re, awon Tira Re, awon Ojise Re ati Ojo Ikeyin, dajudaju o ti sina ni isina t’o jinna tefetefe
إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا ثُمَّ كَفَرُوا ثُمَّ آمَنُوا ثُمَّ كَفَرُوا ثُمَّ ازْدَادُوا كُفْرًا لَمْ يَكُنِ اللَّهُ لِيَغْفِرَ لَهُمْ وَلَا لِيَهْدِيَهُمْ سَبِيلًا
Dajudaju awon t’o gbagbo, leyin naa won sai gbagbo, leyin naa won gbagbo, leyin naa won sai gbagbo, leyin naa won si lekun si i ninu aigbagbo, Allahu ko nii fori jin won, ko si nii fi ona mo won
بَشِّرِ الْمُنَافِقِينَ بِأَنَّ لَهُمْ عَذَابًا أَلِيمًا
Fun awon sobe-selu musulumi ni iro pe dajudaju iya eleta elero n be fun won
الَّذِينَ يَتَّخِذُونَ الْكَافِرِينَ أَوْلِيَاءَ مِنْ دُونِ الْمُؤْمِنِينَ ۚ أَيَبْتَغُونَ عِنْدَهُمُ الْعِزَّةَ فَإِنَّ الْعِزَّةَ لِلَّهِ جَمِيعًا
(Awon ni) awon t’o n mu awon alaigbagbo ni ore ayo leyin awon onigbagbo ododo. Se e n wa agbara lodo won ni? Dajudaju ti Allahu ni gbogbo agbara patapata

Choose other languages: