Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Qasas Ayahs #76 Translated in Yoruba

قُلْ أَرَأَيْتُمْ إِنْ جَعَلَ اللَّهُ عَلَيْكُمُ النَّهَارَ سَرْمَدًا إِلَىٰ يَوْمِ الْقِيَامَةِ مَنْ إِلَٰهٌ غَيْرُ اللَّهِ يَأْتِيكُمْ بِلَيْلٍ تَسْكُنُونَ فِيهِ ۖ أَفَلَا تُبْصِرُونَ
So pe: " E so fun mi, ti Allahu ba so osan di ohun ti o maa wa titi laelae fun yin di Ojo Ajinde, olohun wo leyin Allahu l’o maa fun yin ni ale ti e oo maa sinmi ninu re? Se e o riran ni?”
وَمِنْ رَحْمَتِهِ جَعَلَ لَكُمُ اللَّيْلَ وَالنَّهَارَ لِتَسْكُنُوا فِيهِ وَلِتَبْتَغُوا مِنْ فَضْلِهِ وَلَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ
Ninu ike Re (ni pe) O se oru ati osan fun yin; nitori ki e le sinmi ninu (oru) ati nitori ki e le wa ninu oore Re (ni osan) ati nitori ki e le dupe
وَيَوْمَ يُنَادِيهِمْ فَيَقُولُ أَيْنَ شُرَكَائِيَ الَّذِينَ كُنْتُمْ تَزْعُمُونَ
(Ranti) ojo ti (Allahu) yoo pe won, O si maa so pe: “Nibo ni awon akegbe Mi ti e n so nipa won lai ni eri lowo wa?”
وَنَزَعْنَا مِنْ كُلِّ أُمَّةٍ شَهِيدًا فَقُلْنَا هَاتُوا بُرْهَانَكُمْ فَعَلِمُوا أَنَّ الْحَقَّ لِلَّهِ وَضَلَّ عَنْهُمْ مَا كَانُوا يَفْتَرُونَ
A si maa mu elerii kan jade ninu ijo kookan. A maa so pe: “E mu idi oro yin wa.” Nigba naa, won yoo mo pe dajudaju ododo n je ti Allahu. Ohun ti won si n da ni adapa iro yo si dofo mo won lowo
إِنَّ قَارُونَ كَانَ مِنْ قَوْمِ مُوسَىٰ فَبَغَىٰ عَلَيْهِمْ ۖ وَآتَيْنَاهُ مِنَ الْكُنُوزِ مَا إِنَّ مَفَاتِحَهُ لَتَنُوءُ بِالْعُصْبَةِ أُولِي الْقُوَّةِ إِذْ قَالَ لَهُ قَوْمُهُ لَا تَفْرَحْ ۖ إِنَّ اللَّهَ لَا يُحِبُّ الْفَرِحِينَ
Dajudaju Ƙorun wa ninu ijo (Anabi) Musa, sugbon o segberaga si won. A si fun un ni awon apoti-oro eyi ti awon kokoro re wuwo lati gbe fun opo eniyan, awon alagbara. (Ranti) nigba ti awon eniyan re so fun un pe: "Ma se yo ayo ayoju. Dajudaju Allahu ko feran awon alayoju

Choose other languages: