Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Qasas Ayahs #75 Translated in Yoruba

قُلْ أَرَأَيْتُمْ إِنْ جَعَلَ اللَّهُ عَلَيْكُمُ اللَّيْلَ سَرْمَدًا إِلَىٰ يَوْمِ الْقِيَامَةِ مَنْ إِلَٰهٌ غَيْرُ اللَّهِ يَأْتِيكُمْ بِضِيَاءٍ ۖ أَفَلَا تَسْمَعُونَ
So pe: " E so fun mi, ti Allahu ba so oru di ohun ti o maa wa titi laelae fun yin di Ojo Ajinde, olohun wo leyin Allahu l’o maa fun yin ni imole? Se e o gboro ni?”
قُلْ أَرَأَيْتُمْ إِنْ جَعَلَ اللَّهُ عَلَيْكُمُ النَّهَارَ سَرْمَدًا إِلَىٰ يَوْمِ الْقِيَامَةِ مَنْ إِلَٰهٌ غَيْرُ اللَّهِ يَأْتِيكُمْ بِلَيْلٍ تَسْكُنُونَ فِيهِ ۖ أَفَلَا تُبْصِرُونَ
So pe: " E so fun mi, ti Allahu ba so osan di ohun ti o maa wa titi laelae fun yin di Ojo Ajinde, olohun wo leyin Allahu l’o maa fun yin ni ale ti e oo maa sinmi ninu re? Se e o riran ni?”
وَمِنْ رَحْمَتِهِ جَعَلَ لَكُمُ اللَّيْلَ وَالنَّهَارَ لِتَسْكُنُوا فِيهِ وَلِتَبْتَغُوا مِنْ فَضْلِهِ وَلَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ
Ninu ike Re (ni pe) O se oru ati osan fun yin; nitori ki e le sinmi ninu (oru) ati nitori ki e le wa ninu oore Re (ni osan) ati nitori ki e le dupe
وَيَوْمَ يُنَادِيهِمْ فَيَقُولُ أَيْنَ شُرَكَائِيَ الَّذِينَ كُنْتُمْ تَزْعُمُونَ
(Ranti) ojo ti (Allahu) yoo pe won, O si maa so pe: “Nibo ni awon akegbe Mi ti e n so nipa won lai ni eri lowo wa?”
وَنَزَعْنَا مِنْ كُلِّ أُمَّةٍ شَهِيدًا فَقُلْنَا هَاتُوا بُرْهَانَكُمْ فَعَلِمُوا أَنَّ الْحَقَّ لِلَّهِ وَضَلَّ عَنْهُمْ مَا كَانُوا يَفْتَرُونَ
A si maa mu elerii kan jade ninu ijo kookan. A maa so pe: “E mu idi oro yin wa.” Nigba naa, won yoo mo pe dajudaju ododo n je ti Allahu. Ohun ti won si n da ni adapa iro yo si dofo mo won lowo

Choose other languages: