Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Maeda Ayahs #75 Translated in Yoruba

وَحَسِبُوا أَلَّا تَكُونَ فِتْنَةٌ فَعَمُوا وَصَمُّوا ثُمَّ تَابَ اللَّهُ عَلَيْهِمْ ثُمَّ عَمُوا وَصَمُّوا كَثِيرٌ مِنْهُمْ ۚ وَاللَّهُ بَصِيرٌ بِمَا يَعْمَلُونَ
Won si lero pe ko nii si ifooro; won foju, won si diti (si ododo). Leyin naa, Allahu gba ironupiwada won. Leyin naa, won foju, won tun diti (si ododo); opolopo ninu won (lo se bee). Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti won n se nise
لَقَدْ كَفَرَ الَّذِينَ قَالُوا إِنَّ اللَّهَ هُوَ الْمَسِيحُ ابْنُ مَرْيَمَ ۖ وَقَالَ الْمَسِيحُ يَا بَنِي إِسْرَائِيلَ اعْبُدُوا اللَّهَ رَبِّي وَرَبَّكُمْ ۖ إِنَّهُ مَنْ يُشْرِكْ بِاللَّهِ فَقَدْ حَرَّمَ اللَّهُ عَلَيْهِ الْجَنَّةَ وَمَأْوَاهُ النَّارُ ۖ وَمَا لِلظَّالِمِينَ مِنْ أَنْصَارٍ
Won kuku ti di keferi, awon t’o wi pe: “Dajudaju Allahu, Oun ni Mosih omo Moryam.” Mosih si so pe: "Eyin omo ’Isro’il, e josin fun Allahu, Oluwa mi ati Oluwa yin. Dajudaju enikeni ti o ba ba Allahu wa akegbe, Allahu ti se Ogba Idera ni eewo fun un. Ina si ni ibugbe re. Ko si nii si alaranse kan fun awon alabosi
لَقَدْ كَفَرَ الَّذِينَ قَالُوا إِنَّ اللَّهَ ثَالِثُ ثَلَاثَةٍ ۘ وَمَا مِنْ إِلَٰهٍ إِلَّا إِلَٰهٌ وَاحِدٌ ۚ وَإِنْ لَمْ يَنْتَهُوا عَمَّا يَقُولُونَ لَيَمَسَّنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Won kuku ti di keferi, awon t’o wi pe: “Dajudaju Allahu ni Iketa (awon) meta.” Ko si si olohun kan ti ijosin to si afi Olohun, Okan soso. Ti won ko ba jawo nibi ohun ti won n wi, dajudaju iya eleta elero l’o maa je awon t’o di keferi ninu won
أَفَلَا يَتُوبُونَ إِلَى اللَّهِ وَيَسْتَغْفِرُونَهُ ۚ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَحِيمٌ
Nitori naa, se won ko nii ronu piwada sodo Allahu, ki won si toro aforijin lodo Re? Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun
مَا الْمَسِيحُ ابْنُ مَرْيَمَ إِلَّا رَسُولٌ قَدْ خَلَتْ مِنْ قَبْلِهِ الرُّسُلُ وَأُمُّهُ صِدِّيقَةٌ ۖ كَانَا يَأْكُلَانِ الطَّعَامَ ۗ انْظُرْ كَيْفَ نُبَيِّنُ لَهُمُ الْآيَاتِ ثُمَّ انْظُرْ أَنَّىٰ يُؤْفَكُونَ
Ki ni Mosih bi ko se Ojise kan. Awon Ojise si ti lo siwaju re. Olododo si ni iya re. Awon mejeeji maa n je ounje. Wo bi A se n salaye awon ayah naa. Leyin naa, wo bi won se n seri won kuro nibi ododo

Choose other languages: