Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Maeda Ayahs #77 Translated in Yoruba

لَقَدْ كَفَرَ الَّذِينَ قَالُوا إِنَّ اللَّهَ ثَالِثُ ثَلَاثَةٍ ۘ وَمَا مِنْ إِلَٰهٍ إِلَّا إِلَٰهٌ وَاحِدٌ ۚ وَإِنْ لَمْ يَنْتَهُوا عَمَّا يَقُولُونَ لَيَمَسَّنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Won kuku ti di keferi, awon t’o wi pe: “Dajudaju Allahu ni Iketa (awon) meta.” Ko si si olohun kan ti ijosin to si afi Olohun, Okan soso. Ti won ko ba jawo nibi ohun ti won n wi, dajudaju iya eleta elero l’o maa je awon t’o di keferi ninu won
أَفَلَا يَتُوبُونَ إِلَى اللَّهِ وَيَسْتَغْفِرُونَهُ ۚ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَحِيمٌ
Nitori naa, se won ko nii ronu piwada sodo Allahu, ki won si toro aforijin lodo Re? Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun
مَا الْمَسِيحُ ابْنُ مَرْيَمَ إِلَّا رَسُولٌ قَدْ خَلَتْ مِنْ قَبْلِهِ الرُّسُلُ وَأُمُّهُ صِدِّيقَةٌ ۖ كَانَا يَأْكُلَانِ الطَّعَامَ ۗ انْظُرْ كَيْفَ نُبَيِّنُ لَهُمُ الْآيَاتِ ثُمَّ انْظُرْ أَنَّىٰ يُؤْفَكُونَ
Ki ni Mosih bi ko se Ojise kan. Awon Ojise si ti lo siwaju re. Olododo si ni iya re. Awon mejeeji maa n je ounje. Wo bi A se n salaye awon ayah naa. Leyin naa, wo bi won se n seri won kuro nibi ododo
قُلْ أَتَعْبُدُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ مَا لَا يَمْلِكُ لَكُمْ ضَرًّا وَلَا نَفْعًا ۚ وَاللَّهُ هُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ
So pe: “Se e n josin fun leyin Allahu ohun ti ko ni ikapa inira ati anfaani kan fun yin? Allahu, Oun si ni Olugbo, Onimo.”
قُلْ يَا أَهْلَ الْكِتَابِ لَا تَغْلُوا فِي دِينِكُمْ غَيْرَ الْحَقِّ وَلَا تَتَّبِعُوا أَهْوَاءَ قَوْمٍ قَدْ ضَلُّوا مِنْ قَبْلُ وَأَضَلُّوا كَثِيرًا وَضَلُّوا عَنْ سَوَاءِ السَّبِيلِ
So pe: "Eyin ahlul-kitab, e ma se tayo enu-ala ninu esin yin, ti ki i se (esin) ododo. E ma si se tele ife-inu ijo kan t’o ti sina siwaju (iyen, awon yehudi). Won si opolopo lona. Won si sina kuro ni oju ona taara

Choose other languages: