Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Maeda Ayahs #60 Translated in Yoruba

وَمَنْ يَتَوَلَّ اللَّهَ وَرَسُولَهُ وَالَّذِينَ آمَنُوا فَإِنَّ حِزْبَ اللَّهِ هُمُ الْغَالِبُونَ
Enikeni ti o ba mu Allahu ati Ojise Re ati awon onigbagbo ododo ni ore; dajudaju ijo Allahu, awon ni olubori
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَتَّخِذُوا الَّذِينَ اتَّخَذُوا دِينَكُمْ هُزُوًا وَلَعِبًا مِنَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ مِنْ قَبْلِكُمْ وَالْكُفَّارَ أَوْلِيَاءَ ۚ وَاتَّقُوا اللَّهَ إِنْ كُنْتُمْ مُؤْمِنِينَ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se mu awon t’o so esin yin di nnkan yeye ati ere sise ni ore ninu awon ti A fun ni tira siwaju yin ati awon alaigbagbo. E beru Allahu ti e ba je onigbagbo ododo
وَإِذَا نَادَيْتُمْ إِلَى الصَّلَاةِ اتَّخَذُوهَا هُزُوًا وَلَعِبًا ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ قَوْمٌ لَا يَعْقِلُونَ
Nigba ti e ba pepe sibi irun kiki, won yoo so o di nnkan yeye ati ere sise. Iyen nitori pe dajudaju awon ni ijo ti ko se laakaye
قُلْ يَا أَهْلَ الْكِتَابِ هَلْ تَنْقِمُونَ مِنَّا إِلَّا أَنْ آمَنَّا بِاللَّهِ وَمَا أُنْزِلَ إِلَيْنَا وَمَا أُنْزِلَ مِنْ قَبْلُ وَأَنَّ أَكْثَرَكُمْ فَاسِقُونَ
So pe: “Eyin ahlul-kitab, nje e tako kini kan lara wa bi ko se pe a gbagbo ninu Allahu ati ohun ti Won sokale fun wa ati ohun ti Won sokale siwaju?” Dajudaju opolopo yin ni obileje
قُلْ هَلْ أُنَبِّئُكُمْ بِشَرٍّ مِنْ ذَٰلِكَ مَثُوبَةً عِنْدَ اللَّهِ ۚ مَنْ لَعَنَهُ اللَّهُ وَغَضِبَ عَلَيْهِ وَجَعَلَ مِنْهُمُ الْقِرَدَةَ وَالْخَنَازِيرَ وَعَبَدَ الطَّاغُوتَ ۚ أُولَٰئِكَ شَرٌّ مَكَانًا وَأَضَلُّ عَنْ سَوَاءِ السَّبِيلِ
So pe: “Se ki ng fun yin ni iro awon ti iya won buru ju iyen lo ni odo Allahu?” (Oun ni) eni ti Allahu sebi le, ti O si binu si, ti O si so awon kan ninu won di obo, elede ati aborisa. Awon wonyen ni ipo won buru julo, awon si ni won sina julo

Choose other languages: