Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Kahf Ayahs #61 Translated in Yoruba

وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنْ ذُكِّرَ بِآيَاتِ رَبِّهِ فَأَعْرَضَ عَنْهَا وَنَسِيَ مَا قَدَّمَتْ يَدَاهُ ۚ إِنَّا جَعَلْنَا عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ أَكِنَّةً أَنْ يَفْقَهُوهُ وَفِي آذَانِهِمْ وَقْرًا ۖ وَإِنْ تَدْعُهُمْ إِلَى الْهُدَىٰ فَلَنْ يَهْتَدُوا إِذًا أَبَدًا
Ta si l’o sabosi ju eni ti won fi awon ayah Oluwa re seranti fun, ti o gbunri kuro nibe, ti o si gbagbe ohun ti owo re mejeeji ti siwaju? Dajudaju Awa fi ebibo bo okan won nitori ki won ma baa gbo o ye. A si fi edidi sinu eti won. Ti iwo ba pe won sinu imona, nigba naa won ko si nii mona laelae
وَرَبُّكَ الْغَفُورُ ذُو الرَّحْمَةِ ۖ لَوْ يُؤَاخِذُهُمْ بِمَا كَسَبُوا لَعَجَّلَ لَهُمُ الْعَذَابَ ۚ بَلْ لَهُمْ مَوْعِدٌ لَنْ يَجِدُوا مِنْ دُونِهِ مَوْئِلًا
Oluwa re, Alaforijin, Onikee, ti o ba je pe O maa fi ohun ti won se nise mu won ni, iba tete mu iya wa fun won. Sugbon akoko adehun (ajinde) wa fun won. Won ko si nii ri ibusasi kan leyin re
وَتِلْكَ الْقُرَىٰ أَهْلَكْنَاهُمْ لَمَّا ظَلَمُوا وَجَعَلْنَا لِمَهْلِكِهِمْ مَوْعِدًا
Iwonyi ni awon ilu ti A ti pare nigba ti won sabosi. A si fun won ni adehun fun iparun won
وَإِذْ قَالَ مُوسَىٰ لِفَتَاهُ لَا أَبْرَحُ حَتَّىٰ أَبْلُغَ مَجْمَعَ الْبَحْرَيْنِ أَوْ أَمْضِيَ حُقُبًا
(Ranti) nigba ti (Anabi) Musa so fun omo-odo re pe: "Ng o nii ye rin titi mo maa fi de ibi ti odo meji ti pade tabi (titi) mo maa fi lo opolopo odun
فَلَمَّا بَلَغَا مَجْمَعَ بَيْنِهِمَا نَسِيَا حُوتَهُمَا فَاتَّخَذَ سَبِيلَهُ فِي الْبَحْرِ سَرَبًا
Nigba ti awon mejeeji si de ibi ti odo meji ti pade, won gbagbe eja won. (Eja naa) si bo si oju ona re (ti o ti di) poro ona ninu odo

Choose other languages: