Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Isra Ayahs #109 Translated in Yoruba

وَبِالْحَقِّ أَنْزَلْنَاهُ وَبِالْحَقِّ نَزَلَ ۗ وَمَا أَرْسَلْنَاكَ إِلَّا مُبَشِّرًا وَنَذِيرًا
A so al-Ƙur’an kale pelu ododo. O si sokale pelu ododo. A ko si ran o nise bi ko se pe (ki o je) oniroo-idunnu ati olukilo
وَقُرْآنًا فَرَقْنَاهُ لِتَقْرَأَهُ عَلَى النَّاسِ عَلَىٰ مُكْثٍ وَنَزَّلْنَاهُ تَنْزِيلًا
Ati pe al-Ƙur’an, A salaye re (fun o) nitori ki o le ke e fun awon eniyan pelu pelepele. A si so o kale diedie. orisi isokale meji l’o wa fun al-Ƙur’an. Isokale kiini ni isokale olodidi lati inu Laohul-Mahfuth sinu sanmo ile aye. Isokale yii l’o sele ninu oru Laelatul-ƙodr. Eyi l’o jeyo ninu surah al-Baƙorah; 2:185 surah ad-Dukan; 44:3 ati surah al-Ƙodr’ 97:1. Isokale keji ni isokale onidiedie lati inu sanmo ile aye sori ile aye. Eyi sele fun onka odun metalelogun. Isokale yii ni ayah yii n so nipa re
قُلْ آمِنُوا بِهِ أَوْ لَا تُؤْمِنُوا ۚ إِنَّ الَّذِينَ أُوتُوا الْعِلْمَ مِنْ قَبْلِهِ إِذَا يُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ يَخِرُّونَ لِلْأَذْقَانِ سُجَّدًا
So pe: “E gba al-Ƙur’an gbo tabi e o gba a gbo, dajudaju awon ti A fun ni imo siwaju (isokale) re, nigba ti won ba n ke e fun won, won yoo doju bole, ti won n fori kanle (fun Allahu)
وَيَقُولُونَ سُبْحَانَ رَبِّنَا إِنْ كَانَ وَعْدُ رَبِّنَا لَمَفْعُولًا
Won n so pe: “Mimo ni fun Oluwa wa. Dajudaju adehun Oluwa wa maa wa si imuse ni.”
وَيَخِرُّونَ لِلْأَذْقَانِ يَبْكُونَ وَيَزِيدُهُمْ خُشُوعًا ۩
Won n doju bole, ti won n sunkun (fun Allahu. Al-Ƙur’an) si n salekun iteriba fun won

Choose other languages: