Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Isra Ayahs #110 Translated in Yoruba

وَقُرْآنًا فَرَقْنَاهُ لِتَقْرَأَهُ عَلَى النَّاسِ عَلَىٰ مُكْثٍ وَنَزَّلْنَاهُ تَنْزِيلًا
Ati pe al-Ƙur’an, A salaye re (fun o) nitori ki o le ke e fun awon eniyan pelu pelepele. A si so o kale diedie. orisi isokale meji l’o wa fun al-Ƙur’an. Isokale kiini ni isokale olodidi lati inu Laohul-Mahfuth sinu sanmo ile aye. Isokale yii l’o sele ninu oru Laelatul-ƙodr. Eyi l’o jeyo ninu surah al-Baƙorah; 2:185 surah ad-Dukan; 44:3 ati surah al-Ƙodr’ 97:1. Isokale keji ni isokale onidiedie lati inu sanmo ile aye sori ile aye. Eyi sele fun onka odun metalelogun. Isokale yii ni ayah yii n so nipa re
قُلْ آمِنُوا بِهِ أَوْ لَا تُؤْمِنُوا ۚ إِنَّ الَّذِينَ أُوتُوا الْعِلْمَ مِنْ قَبْلِهِ إِذَا يُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ يَخِرُّونَ لِلْأَذْقَانِ سُجَّدًا
So pe: “E gba al-Ƙur’an gbo tabi e o gba a gbo, dajudaju awon ti A fun ni imo siwaju (isokale) re, nigba ti won ba n ke e fun won, won yoo doju bole, ti won n fori kanle (fun Allahu)
وَيَقُولُونَ سُبْحَانَ رَبِّنَا إِنْ كَانَ وَعْدُ رَبِّنَا لَمَفْعُولًا
Won n so pe: “Mimo ni fun Oluwa wa. Dajudaju adehun Oluwa wa maa wa si imuse ni.”
وَيَخِرُّونَ لِلْأَذْقَانِ يَبْكُونَ وَيَزِيدُهُمْ خُشُوعًا ۩
Won n doju bole, ti won n sunkun (fun Allahu. Al-Ƙur’an) si n salekun iteriba fun won
قُلِ ادْعُوا اللَّهَ أَوِ ادْعُوا الرَّحْمَٰنَ ۖ أَيًّا مَا تَدْعُوا فَلَهُ الْأَسْمَاءُ الْحُسْنَىٰ ۚ وَلَا تَجْهَرْ بِصَلَاتِكَ وَلَا تُخَافِتْ بِهَا وَابْتَغِ بَيْنَ ذَٰلِكَ سَبِيلًا
So pe: “E pe Allahu tabi e pe ar-Rahmon (Ajoke-aye).” Eyikeyii ti e ba fi pe E (ninu re), sebi tiRe ni awon oruko t’o dara julo. Ma se kigbe lori irun (ati adua) re. Ma si se wa ni idake roro. Wa ona saaarin mejeeji yen

Choose other languages: