Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Hadid Ayahs #26 Translated in Yoruba

مَا أَصَابَ مِنْ مُصِيبَةٍ فِي الْأَرْضِ وَلَا فِي أَنْفُسِكُمْ إِلَّا فِي كِتَابٍ مِنْ قَبْلِ أَنْ نَبْرَأَهَا ۚ إِنَّ ذَٰلِكَ عَلَى اللَّهِ يَسِيرٌ
Adanwo kan ko nii sele ni ori ile tabi (ki o sele) si eyin ayafi ki o ti wa ninu Tira siwaju ki A t’o da eda. Dajudaju iyen rorun fun Allahu
لِكَيْلَا تَأْسَوْا عَلَىٰ مَا فَاتَكُمْ وَلَا تَفْرَحُوا بِمَا آتَاكُمْ ۗ وَاللَّهُ لَا يُحِبُّ كُلَّ مُخْتَالٍ فَخُورٍ
(Isele n to kadara leyin) nitori ki e ma se banuje lori ohun ti o ba bo fun yin ati nitori ki e ma se yo ayoju lori ohun ti O ba fun yin. Allahu ko si nifee si gbogbo onigbeeraga, onifaari
الَّذِينَ يَبْخَلُونَ وَيَأْمُرُونَ النَّاسَ بِالْبُخْلِ ۗ وَمَنْ يَتَوَلَّ فَإِنَّ اللَّهَ هُوَ الْغَنِيُّ الْحَمِيدُ
Awon t’o n sahun, ti won si n pa awon eniyan lase ahun sise (ki won mo pe) enikeni ti o ba peyinda (ti ko nawo fun esin), dajudaju Allahu, Oun ni Oloro, Olope
لَقَدْ أَرْسَلْنَا رُسُلَنَا بِالْبَيِّنَاتِ وَأَنْزَلْنَا مَعَهُمُ الْكِتَابَ وَالْمِيزَانَ لِيَقُومَ النَّاسُ بِالْقِسْطِ ۖ وَأَنْزَلْنَا الْحَدِيدَ فِيهِ بَأْسٌ شَدِيدٌ وَمَنَافِعُ لِلنَّاسِ وَلِيَعْلَمَ اللَّهُ مَنْ يَنْصُرُهُ وَرُسُلَهُ بِالْغَيْبِ ۚ إِنَّ اللَّهَ قَوِيٌّ عَزِيزٌ
Dajudaju A fi awon eri t’o yanju ran awon Ojise Wa. A so Tira kale fun won ati osuwon nitori ki awon eniyan le ri deede se (laaarin ara won). A tun so irin kale. Ohun ijagun t’o lagbara ati awon anfaani wa ninu re fun awon eniyan nitori ki Allahu le safi han eni t’o n ran (esin) Re ati Ojise Re lowo ni ikoko. Dajudaju Allahu ni Alagbara, Olubori
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا نُوحًا وَإِبْرَاهِيمَ وَجَعَلْنَا فِي ذُرِّيَّتِهِمَا النُّبُوَّةَ وَالْكِتَابَ ۖ فَمِنْهُمْ مُهْتَدٍ ۖ وَكَثِيرٌ مِنْهُمْ فَاسِقُونَ
Dajudaju A fi ise ran (Anabi) Nuh ati (Anabi) ’Ibrohim. A fi ipo Anabi sinu awon aromodomo awon mejeeji pelu Tira (ti A fun won). Olumona wa ninu won. Opolopo ninu won si ni obileje

Choose other languages: