Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #244 Translated in Yoruba

وَالَّذِينَ يُتَوَفَّوْنَ مِنْكُمْ وَيَذَرُونَ أَزْوَاجًا وَصِيَّةً لِأَزْوَاجِهِمْ مَتَاعًا إِلَى الْحَوْلِ غَيْرَ إِخْرَاجٍ ۚ فَإِنْ خَرَجْنَ فَلَا جُنَاحَ عَلَيْكُمْ فِي مَا فَعَلْنَ فِي أَنْفُسِهِنَّ مِنْ مَعْرُوفٍ ۗ وَاللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ
Awon ti won ku ninu yin, ti won si fi awon iyawo saye lo, ki won se asoole ije-imu odun kan fun awon iyawo won, lai si nii le won jade kuro ninu ile won. Ti won ba si jade (funra won leyin ijade opo), ko si ese fun yin nipa ohun ti won ba fi’ra won se ni daadaa (lati ni oko miiran). Allahu ni Alagbara, Ologbon
وَلِلْمُطَلَّقَاتِ مَتَاعٌ بِالْمَعْرُوفِ ۖ حَقًّا عَلَى الْمُتَّقِينَ
Nnkan igbadun ni ona t’o dara tun maa wa fun awon obinrin ti won kosile. Ojuse l’o je fun awon oluberu Allahu
كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ اللَّهُ لَكُمْ آيَاتِهِ لَعَلَّكُمْ تَعْقِلُونَ
Bayen ni Allahu se n salaye awon ayah Re fun yin, nitori ki e le se laakaye
أَلَمْ تَرَ إِلَى الَّذِينَ خَرَجُوا مِنْ دِيَارِهِمْ وَهُمْ أُلُوفٌ حَذَرَ الْمَوْتِ فَقَالَ لَهُمُ اللَّهُ مُوتُوا ثُمَّ أَحْيَاهُمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ لَذُو فَضْلٍ عَلَى النَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَشْكُرُونَ
Se o o ri awon t’o jade lati inu ile won legbeegberun nitori iberu iku! Allahu si so fun won pe: “E ku.” Leyin naa, O so won di alaaye. Dajudaju Allahu ni Oloore-ajulo lori awon eniyan, sugbon opolopo eniyan ko dupe (fun Un)
وَقَاتِلُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ وَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ سَمِيعٌ عَلِيمٌ
E jagun fun aabo esin Allahu, ki e si mo pe dajudaju Allahu ni Olugbo, Onimo

Choose other languages: