Surah Al-Baqara Ayahs #239 Translated in Yoruba
وَلَا جُنَاحَ عَلَيْكُمْ فِيمَا عَرَّضْتُمْ بِهِ مِنْ خِطْبَةِ النِّسَاءِ أَوْ أَكْنَنْتُمْ فِي أَنْفُسِكُمْ ۚ عَلِمَ اللَّهُ أَنَّكُمْ سَتَذْكُرُونَهُنَّ وَلَٰكِنْ لَا تُوَاعِدُوهُنَّ سِرًّا إِلَّا أَنْ تَقُولُوا قَوْلًا مَعْرُوفًا ۚ وَلَا تَعْزِمُوا عُقْدَةَ النِّكَاحِ حَتَّىٰ يَبْلُغَ الْكِتَابُ أَجَلَهُ ۚ وَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ يَعْلَمُ مَا فِي أَنْفُسِكُمْ فَاحْذَرُوهُ ۚ وَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ غَفُورٌ حَلِيمٌ
Ko si si ese fun yin nipa ohun ti e peso ninu ibanisoro ife tabi ti e fi pamo sinu emi yin. Allahu mo pe dajudaju eyin yo maa ranti won, sugbon e ma se ba won se adehun ni ikoko, ayafi pe ki e maa so oro daadaa. E ma se pinnu ita koko yigi titi asiko (opo) maa fi pari. E mo pe dajudaju Allahu mo ohun ti n be ninu emi yin, nitori naa, e beru Re. Ki e si mo pe dajudaju Allahu ni Alaforijin, Alafarada
لَا جُنَاحَ عَلَيْكُمْ إِنْ طَلَّقْتُمُ النِّسَاءَ مَا لَمْ تَمَسُّوهُنَّ أَوْ تَفْرِضُوا لَهُنَّ فَرِيضَةً ۚ وَمَتِّعُوهُنَّ عَلَى الْمُوسِعِ قَدَرُهُ وَعَلَى الْمُقْتِرِ قَدَرُهُ مَتَاعًا بِالْمَعْرُوفِ ۖ حَقًّا عَلَى الْمُحْسِنِينَ
Ko si ese fun yin, ti e ba ko awon obinrin sile, lai ti i sunmo won tabi lai ti i so odiwon sodaaki kan fun won ni pato. Ki e si fun won ni ebun (ikosile); ki olugbooro (ninu arisiki) fi iwon (agbara) re sile, ki talika si fi iwon (agbara) re sile ni ona t’o dara. Ojuse l’o je fun awon oluse-rere
وَإِنْ طَلَّقْتُمُوهُنَّ مِنْ قَبْلِ أَنْ تَمَسُّوهُنَّ وَقَدْ فَرَضْتُمْ لَهُنَّ فَرِيضَةً فَنِصْفُ مَا فَرَضْتُمْ إِلَّا أَنْ يَعْفُونَ أَوْ يَعْفُوَ الَّذِي بِيَدِهِ عُقْدَةُ النِّكَاحِ ۚ وَأَنْ تَعْفُوا أَقْرَبُ لِلتَّقْوَىٰ ۚ وَلَا تَنْسَوُا الْفَضْلَ بَيْنَكُمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ
Ti e ba si ko won sile siwaju ki e to sunmo won, ti e si ti so odiwon sodaaki kan fun won, ilaji ohun ti e ti sodiwon re ni sodaaki (ni ki e fun won), afi ti won ba samoju kuro (fun gbogbo re, iyen awon obinrin) tabi ti eni ti koko yigi n be ni owo re ba samoju kuro (fun gbogbo re, iyen awon oko). Ki e samoju kuro lo sunmo iberu Allahu julo. E ma se gbagbe oore ajulo aarin yin. Dajudaju Allahu ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise
حَافِظُوا عَلَى الصَّلَوَاتِ وَالصَّلَاةِ الْوُسْطَىٰ وَقُومُوا لِلَّهِ قَانِتِينَ
E so awon irun (wakati maraarun) ati (ni paapaa julo) irun aarin. Ki e si duro (kirun gege bi) oluteriba fun Allahu, lai nii soro (miiran lori irun)
فَإِنْ خِفْتُمْ فَرِجَالًا أَوْ رُكْبَانًا ۖ فَإِذَا أَمِنْتُمْ فَاذْكُرُوا اللَّهَ كَمَا عَلَّمَكُمْ مَا لَمْ تَكُونُوا تَعْلَمُونَ
Sugbon ti e ba n beru (ota l’oju ogun esin), e kirun yin lori irin (ese) tabi lori nnkan igun. Nigba ti okan yin ba si bale, e kirun fun Allahu gege bi O se fi ohun ti eyin ko mo (tele) mo yin
Choose other languages:

Albanian

Amharic

Azerbaijani

Bengali

Bosnian

Bulgarian

Burmese

Chinese

Danish

Dutch

English

Farsi

Filipino

French

Fulah

German

Gujarati

Hausa

Hindi

Indonesian

Italian

Japanese

Jawa

Kazakh

Khmer

Korean

Kurdish

Kyrgyz

Malay

Malayalam

Norwegian

Pashto

Persian

Polish

Portuguese

Punjabi

Russian

Sindhi

Sinhalese

Somali

Spanish

Swahili

Swedish

Tajik

Tamil

Tatar

Telugu

Thai

Turkish

Urdu

Uyghur

Uzbek

Vietnamese

Yoruba
