Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #236 Translated in Yoruba

وَإِذَا طَلَّقْتُمُ النِّسَاءَ فَبَلَغْنَ أَجَلَهُنَّ فَلَا تَعْضُلُوهُنَّ أَنْ يَنْكِحْنَ أَزْوَاجَهُنَّ إِذَا تَرَاضَوْا بَيْنَهُمْ بِالْمَعْرُوفِ ۗ ذَٰلِكَ يُوعَظُ بِهِ مَنْ كَانَ مِنْكُمْ يُؤْمِنُ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ ۗ ذَٰلِكُمْ أَزْكَىٰ لَكُمْ وَأَطْهَرُ ۗ وَاللَّهُ يَعْلَمُ وَأَنْتُمْ لَا تَعْلَمُونَ
Nigba ti e ba ko awon obinrin sile (ni ee kini tabi ee keji), ti won si pari asiko (opo) won, e ma se di won lowo lati fe oko won, nigba ti won ba jo yonu sira won (ti won si gba) ona to dara . Iyen ni A n fi se waasi fun enikeni ninu yin, t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin. Iyen l’o fo yin mo julo. O si tun safomo (okan yin) julo. Allahu nimo, eyin ko si nimo
وَالْوَالِدَاتُ يُرْضِعْنَ أَوْلَادَهُنَّ حَوْلَيْنِ كَامِلَيْنِ ۖ لِمَنْ أَرَادَ أَنْ يُتِمَّ الرَّضَاعَةَ ۚ وَعَلَى الْمَوْلُودِ لَهُ رِزْقُهُنَّ وَكِسْوَتُهُنَّ بِالْمَعْرُوفِ ۚ لَا تُكَلَّفُ نَفْسٌ إِلَّا وُسْعَهَا ۚ لَا تُضَارَّ وَالِدَةٌ بِوَلَدِهَا وَلَا مَوْلُودٌ لَهُ بِوَلَدِهِ ۚ وَعَلَى الْوَارِثِ مِثْلُ ذَٰلِكَ ۗ فَإِنْ أَرَادَا فِصَالًا عَنْ تَرَاضٍ مِنْهُمَا وَتَشَاوُرٍ فَلَا جُنَاحَ عَلَيْهِمَا ۗ وَإِنْ أَرَدْتُمْ أَنْ تَسْتَرْضِعُوا أَوْلَادَكُمْ فَلَا جُنَاحَ عَلَيْكُمْ إِذَا سَلَّمْتُمْ مَا آتَيْتُمْ بِالْمَعْرُوفِ ۗ وَاتَّقُوا اللَّهَ وَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ
Awon abiyamo yoo maa fun awon omo won ni oyan mu fun odun meji gbako, fun eni ti o ba fe pari (asiko) ifomoloyan. Ojuse ni fun eni ti won bimo fun lati maa se (eto) ije-imu won ati aso won ni ona t’o dara. Won ko labo emi kan lorun afi iwon agbara re. Won ko nii ko inira ba abiyamo nitori omo re. Won ko si nii ko inira ba eni ti won bimo fun nitori omo re. Iru (ojuse) yen tun n be fun olujogun. Ti awon mejeeji ba si fe gba oyan l’enu omo pelu ipanupo ati asaro awon mejeeji, ko si ese fun awon mejeeji. Ti e ba si fe gba eni ti o maa fun awon omo yin loyan mu, ko si ese fun yin, ti e ba ti fun won ni ohun ti e fe fun won (ni owo-oya) ni ona t’o dara. E beru Allahu. Ki e si mo pe dajudaju Allahu ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise
وَالَّذِينَ يُتَوَفَّوْنَ مِنْكُمْ وَيَذَرُونَ أَزْوَاجًا يَتَرَبَّصْنَ بِأَنْفُسِهِنَّ أَرْبَعَةَ أَشْهُرٍ وَعَشْرًا ۖ فَإِذَا بَلَغْنَ أَجَلَهُنَّ فَلَا جُنَاحَ عَلَيْكُمْ فِيمَا فَعَلْنَ فِي أَنْفُسِهِنَّ بِالْمَعْرُوفِ ۗ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرٌ
Awon ti oko won ku ninu yin, ti won si fi awon iyawo sile, won yoo kora ro fun osu merin ati ojo mewaa. Nigba ti won ba pari asiko (opo) won, ko si ese fun yin nipa ohun ti won ba se funra won (lati ni oko miiran) ni ona t’o dara. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise
وَلَا جُنَاحَ عَلَيْكُمْ فِيمَا عَرَّضْتُمْ بِهِ مِنْ خِطْبَةِ النِّسَاءِ أَوْ أَكْنَنْتُمْ فِي أَنْفُسِكُمْ ۚ عَلِمَ اللَّهُ أَنَّكُمْ سَتَذْكُرُونَهُنَّ وَلَٰكِنْ لَا تُوَاعِدُوهُنَّ سِرًّا إِلَّا أَنْ تَقُولُوا قَوْلًا مَعْرُوفًا ۚ وَلَا تَعْزِمُوا عُقْدَةَ النِّكَاحِ حَتَّىٰ يَبْلُغَ الْكِتَابُ أَجَلَهُ ۚ وَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ يَعْلَمُ مَا فِي أَنْفُسِكُمْ فَاحْذَرُوهُ ۚ وَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ غَفُورٌ حَلِيمٌ
Ko si si ese fun yin nipa ohun ti e peso ninu ibanisoro ife tabi ti e fi pamo sinu emi yin. Allahu mo pe dajudaju eyin yo maa ranti won, sugbon e ma se ba won se adehun ni ikoko, ayafi pe ki e maa so oro daadaa. E ma se pinnu ita koko yigi titi asiko (opo) maa fi pari. E mo pe dajudaju Allahu mo ohun ti n be ninu emi yin, nitori naa, e beru Re. Ki e si mo pe dajudaju Allahu ni Alaforijin, Alafarada
لَا جُنَاحَ عَلَيْكُمْ إِنْ طَلَّقْتُمُ النِّسَاءَ مَا لَمْ تَمَسُّوهُنَّ أَوْ تَفْرِضُوا لَهُنَّ فَرِيضَةً ۚ وَمَتِّعُوهُنَّ عَلَى الْمُوسِعِ قَدَرُهُ وَعَلَى الْمُقْتِرِ قَدَرُهُ مَتَاعًا بِالْمَعْرُوفِ ۖ حَقًّا عَلَى الْمُحْسِنِينَ
Ko si ese fun yin, ti e ba ko awon obinrin sile, lai ti i sunmo won tabi lai ti i so odiwon sodaaki kan fun won ni pato. Ki e si fun won ni ebun (ikosile); ki olugbooro (ninu arisiki) fi iwon (agbara) re sile, ki talika si fi iwon (agbara) re sile ni ona t’o dara. Ojuse l’o je fun awon oluse-rere

Choose other languages: