Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #182 Translated in Yoruba

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا كُتِبَ عَلَيْكُمُ الْقِصَاصُ فِي الْقَتْلَى ۖ الْحُرُّ بِالْحُرِّ وَالْعَبْدُ بِالْعَبْدِ وَالْأُنْثَىٰ بِالْأُنْثَىٰ ۚ فَمَنْ عُفِيَ لَهُ مِنْ أَخِيهِ شَيْءٌ فَاتِّبَاعٌ بِالْمَعْرُوفِ وَأَدَاءٌ إِلَيْهِ بِإِحْسَانٍ ۗ ذَٰلِكَ تَخْفِيفٌ مِنْ رَبِّكُمْ وَرَحْمَةٌ ۗ فَمَنِ اعْتَدَىٰ بَعْدَ ذَٰلِكَ فَلَهُ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, A se esan gbigba nibi ipaniyan ni oran- anyan fun yin. Olominira fun olominira, eru fun eru, obinrin fun obinrin. Enikeni ti won ba samoju kuro kini kan fun lati odo omo iya (eni ti won pa, ki eni ti o maa gba owo emi dipo emi) se ohun rere tele (owo ti o gba, ki eni ti o maa san’wo emi) san owo naa fun un ni ona t’o dara. Iyen ni igbefuye ati aanu lati odo Oluwa yin. Sugbon enikeni ti o ba tayo enu-ala (ofin) leyin iyen, iya eleta-elero n be fun un
وَلَكُمْ فِي الْقِصَاصِ حَيَاةٌ يَا أُولِي الْأَلْبَابِ لَعَلَّكُمْ تَتَّقُونَ
Isemi wa fun yin ninu (ofin) igbesan ipaniyan, eyin onilaakaye, ki e le beru (Allahu)
كُتِبَ عَلَيْكُمْ إِذَا حَضَرَ أَحَدَكُمُ الْمَوْتُ إِنْ تَرَكَ خَيْرًا الْوَصِيَّةُ لِلْوَالِدَيْنِ وَالْأَقْرَبِينَ بِالْمَعْرُوفِ ۖ حَقًّا عَلَى الْمُتَّقِينَ
A se e ni oran-anyan fun yin, nigba ti iku ba de ba eni kan ninu yin, ti o si fi dukia sile, pe ki o so asoole ni ona t’o dara fun awon obi mejeeji ati awon ebi. (Eyi je) ojuse fun awon oluberu (Allahu)
فَمَنْ بَدَّلَهُ بَعْدَمَا سَمِعَهُ فَإِنَّمَا إِثْمُهُ عَلَى الَّذِينَ يُبَدِّلُونَهُ ۚ إِنَّ اللَّهَ سَمِيعٌ عَلِيمٌ
Enikeni ti o ba yi i pada leyin ti o ti gbo o, ese re yo si wa lorun awon t’o n yi i pada. Dajudaju Allahu ni Olugbo, Onimo
فَمَنْ خَافَ مِنْ مُوصٍ جَنَفًا أَوْ إِثْمًا فَأَصْلَحَ بَيْنَهُمْ فَلَا إِثْمَ عَلَيْهِ ۚ إِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَحِيمٌ
Sugbon eni ti o ba beru asise tabi iwa ese lati odo eni ti o so asoole, ti o si se atunse laaarin (awon ti ogun to si). Nitori naa, ko si ese fun un. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

Choose other languages: