Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anfal Ayahs #46 Translated in Yoruba

إِذْ أَنْتُمْ بِالْعُدْوَةِ الدُّنْيَا وَهُمْ بِالْعُدْوَةِ الْقُصْوَىٰ وَالرَّكْبُ أَسْفَلَ مِنْكُمْ ۚ وَلَوْ تَوَاعَدْتُمْ لَاخْتَلَفْتُمْ فِي الْمِيعَادِ ۙ وَلَٰكِنْ لِيَقْضِيَ اللَّهُ أَمْرًا كَانَ مَفْعُولًا لِيَهْلِكَ مَنْ هَلَكَ عَنْ بَيِّنَةٍ وَيَحْيَىٰ مَنْ حَيَّ عَنْ بَيِّنَةٍ ۗ وَإِنَّ اللَّهَ لَسَمِيعٌ عَلِيمٌ
(E ranti) nigba ti eyin wa ni eti koto t’o sunmo (ilu Modinah), awon (keferi) si wa ni eti koto t’o jinna si (ilu Modinah), awon keferi kan t’o n gun nnkan igun (bo lati irin-ajo okowo), won si wa ni isale odo tiyin. Ti o ba je pe eyin ati awon keferi jo mu ojo fun ogun naa ni, eyin iba yapa adehun naa, sugbon (ogun naa sele bee) nitori ki Allahu le mu oro kan ti o gbodo se wa si imuse; nitori ki eni ti o maa parun (sinu aigbagbo) le parun nipase eri t’o yanju, ki eni t’o si maa ye (ninu igbagbo ododo) le ye nipase eri t’o yanju. Ati pe dajudaju Allahu kuku ni Olugbo, Onimo
إِذْ يُرِيكَهُمُ اللَّهُ فِي مَنَامِكَ قَلِيلًا ۖ وَلَوْ أَرَاكَهُمْ كَثِيرًا لَفَشِلْتُمْ وَلَتَنَازَعْتُمْ فِي الْأَمْرِ وَلَٰكِنَّ اللَّهَ سَلَّمَ ۗ إِنَّهُ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ
(Ranti) nigba ti Allahu fi won han o ninu ala re (pe won) kere. Ti o ba je pe O fi won han o (pe won) po ni, eyin iba sojo, eyin iba si sariyanjiyan nipa oro naa. Sugbon Allahu ko (yin) yo. Dajudaju Oun ni Onimo nipa nnkan ti n be ninu igba-aya eda
وَإِذْ يُرِيكُمُوهُمْ إِذِ الْتَقَيْتُمْ فِي أَعْيُنِكُمْ قَلِيلًا وَيُقَلِّلُكُمْ فِي أَعْيُنِهِمْ لِيَقْضِيَ اللَّهُ أَمْرًا كَانَ مَفْعُولًا ۗ وَإِلَى اللَّهِ تُرْجَعُ الْأُمُورُ
(Ranti) nigba ti O n fi won han yin pe won kere loju yin - nigba ti e pade (loju ogun) – O si mu eyin naa kere loju tiwon naa, nitori ki Allahu le mu oro kan ti o gbodo se wa si imuse. Odo Allahu si ni won maa seri awon oro eda pada si
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِذَا لَقِيتُمْ فِئَةً فَاثْبُتُوا وَاذْكُرُوا اللَّهَ كَثِيرًا لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti e ba pade ijo (ogun) kan, e duro sinsin, ki e si se (gbolohun) iranti Allahu ni (onka) pupo nitori ki e le jere
وَأَطِيعُوا اللَّهَ وَرَسُولَهُ وَلَا تَنَازَعُوا فَتَفْشَلُوا وَتَذْهَبَ رِيحُكُمْ ۖ وَاصْبِرُوا ۚ إِنَّ اللَّهَ مَعَ الصَّابِرِينَ
E tele ti Allahu ati Ojise Re. E ma se jara yin niyan (nipa ogun esin) nitori ki e ma baa sojo ati nitori ki agbara yin ma baa kuro lowo yin. E se suuru, dajudaju Allahu wa pelu awon onisuuru

Choose other languages: