Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anfal Ayahs #49 Translated in Yoruba

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِذَا لَقِيتُمْ فِئَةً فَاثْبُتُوا وَاذْكُرُوا اللَّهَ كَثِيرًا لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti e ba pade ijo (ogun) kan, e duro sinsin, ki e si se (gbolohun) iranti Allahu ni (onka) pupo nitori ki e le jere
وَأَطِيعُوا اللَّهَ وَرَسُولَهُ وَلَا تَنَازَعُوا فَتَفْشَلُوا وَتَذْهَبَ رِيحُكُمْ ۖ وَاصْبِرُوا ۚ إِنَّ اللَّهَ مَعَ الصَّابِرِينَ
E tele ti Allahu ati Ojise Re. E ma se jara yin niyan (nipa ogun esin) nitori ki e ma baa sojo ati nitori ki agbara yin ma baa kuro lowo yin. E se suuru, dajudaju Allahu wa pelu awon onisuuru
وَلَا تَكُونُوا كَالَّذِينَ خَرَجُوا مِنْ دِيَارِهِمْ بَطَرًا وَرِئَاءَ النَّاسِ وَيَصُدُّونَ عَنْ سَبِيلِ اللَّهِ ۚ وَاللَّهُ بِمَا يَعْمَلُونَ مُحِيطٌ
E ma se da bi awon t’o jade kuro ninu ile won pelu faaari ati sekarimi. Won si n seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti won n se nise
وَإِذْ زَيَّنَ لَهُمُ الشَّيْطَانُ أَعْمَالَهُمْ وَقَالَ لَا غَالِبَ لَكُمُ الْيَوْمَ مِنَ النَّاسِ وَإِنِّي جَارٌ لَكُمْ ۖ فَلَمَّا تَرَاءَتِ الْفِئَتَانِ نَكَصَ عَلَىٰ عَقِبَيْهِ وَقَالَ إِنِّي بَرِيءٌ مِنْكُمْ إِنِّي أَرَىٰ مَا لَا تَرَوْنَ إِنِّي أَخَافُ اللَّهَ ۚ وَاللَّهُ شَدِيدُ الْعِقَابِ
(Ranti) nigba ti Esu se ise won ni oso fun won, o si wi pe: “Ko si eni ti o maa bori yin lonii ninu awon eniyan. Dajudaju emi ni aladuugbo yin.” Sugbon nigba ti awon ijo ogun mejeeji foju kanra won, o pada seyin, o si fese fee, o wi pe: "Dajudaju emi ti yowo-yose ninu oro yin. Dajudaju emi n ri ohun ti eyin ko ri. Emi n paya Allahu. Allahu si le nibi iya
إِذْ يَقُولُ الْمُنَافِقُونَ وَالَّذِينَ فِي قُلُوبِهِمْ مَرَضٌ غَرَّ هَٰؤُلَاءِ دِينُهُمْ ۗ وَمَنْ يَتَوَكَّلْ عَلَى اللَّهِ فَإِنَّ اللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٌ
(Ranti) nigba ti awon sobe-selu musulumi ati awon ti arun n be ninu okan won wi pe: “Esin awon wonyi tan won je.” Enikeni t’o ba gbarale Allahu, dajudaju Allahu ni Alagbara, Ologbon

Choose other languages: