Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anaam Ayahs #50 Translated in Yoruba

قُلْ أَرَأَيْتُمْ إِنْ أَخَذَ اللَّهُ سَمْعَكُمْ وَأَبْصَارَكُمْ وَخَتَمَ عَلَىٰ قُلُوبِكُمْ مَنْ إِلَٰهٌ غَيْرُ اللَّهِ يَأْتِيكُمْ بِهِ ۗ انْظُرْ كَيْفَ نُصَرِّفُ الْآيَاتِ ثُمَّ هُمْ يَصْدِفُونَ
So pe: " E so fun mi, ti Allahu ba gba igboro yin ati iriran yin, ti O si di okan yin pa, olohun wo leyin Allahu ni o maa mu un wa fun yin? Wo bi A se n mu awon ayah wa loniran-anran ona. Leyin naa, won si n gbunri
قُلْ أَرَأَيْتَكُمْ إِنْ أَتَاكُمْ عَذَابُ اللَّهِ بَغْتَةً أَوْ جَهْرَةً هَلْ يُهْلَكُ إِلَّا الْقَوْمُ الظَّالِمُونَ
So pe: “E so fun mi, ti iya Allahu ba de ba yin ni ojiji tabi ni ojukoju, se won maa pa eni kan run bi ko se ijo alabosi!”
وَمَا نُرْسِلُ الْمُرْسَلِينَ إِلَّا مُبَشِّرِينَ وَمُنْذِرِينَ ۖ فَمَنْ آمَنَ وَأَصْلَحَ فَلَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ
A ko ran awon Ojise naa nise bi ko se pe (ki won je) oniroo idunnu ati olukilo. Nitori naa, enikeni ti o ba gbagbo ni ododo, ti o si se atunse (ise re), ko nii si iberu fun won, won ko si nii banuje
وَالَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا يَمَسُّهُمُ الْعَذَابُ بِمَا كَانُوا يَفْسُقُونَ
Awon t’o si pe awon ayah Wa niro, owo iya yoo te won nitori pe won maa n sebaje
قُلْ لَا أَقُولُ لَكُمْ عِنْدِي خَزَائِنُ اللَّهِ وَلَا أَعْلَمُ الْغَيْبَ وَلَا أَقُولُ لَكُمْ إِنِّي مَلَكٌ ۖ إِنْ أَتَّبِعُ إِلَّا مَا يُوحَىٰ إِلَيَّ ۚ قُلْ هَلْ يَسْتَوِي الْأَعْمَىٰ وَالْبَصِيرُ ۚ أَفَلَا تَتَفَكَّرُونَ
So pe: “Emi ko so fun yin pe awon ile-owo Allahu wa lodo mi, emi ko si nimo ikoko. Emi ko si so fun yin pe molaika kan ni mi. Emi ko tele kini kan ayafi ohun ti Won fi ranse si mi ni imisi.” So pe: "Nje afoju ati oluriran dogba bi? Se e o ronu jinle ni

Choose other languages: