Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anaam Ayahs #52 Translated in Yoruba

وَمَا نُرْسِلُ الْمُرْسَلِينَ إِلَّا مُبَشِّرِينَ وَمُنْذِرِينَ ۖ فَمَنْ آمَنَ وَأَصْلَحَ فَلَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ
A ko ran awon Ojise naa nise bi ko se pe (ki won je) oniroo idunnu ati olukilo. Nitori naa, enikeni ti o ba gbagbo ni ododo, ti o si se atunse (ise re), ko nii si iberu fun won, won ko si nii banuje
وَالَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا يَمَسُّهُمُ الْعَذَابُ بِمَا كَانُوا يَفْسُقُونَ
Awon t’o si pe awon ayah Wa niro, owo iya yoo te won nitori pe won maa n sebaje
قُلْ لَا أَقُولُ لَكُمْ عِنْدِي خَزَائِنُ اللَّهِ وَلَا أَعْلَمُ الْغَيْبَ وَلَا أَقُولُ لَكُمْ إِنِّي مَلَكٌ ۖ إِنْ أَتَّبِعُ إِلَّا مَا يُوحَىٰ إِلَيَّ ۚ قُلْ هَلْ يَسْتَوِي الْأَعْمَىٰ وَالْبَصِيرُ ۚ أَفَلَا تَتَفَكَّرُونَ
So pe: “Emi ko so fun yin pe awon ile-owo Allahu wa lodo mi, emi ko si nimo ikoko. Emi ko si so fun yin pe molaika kan ni mi. Emi ko tele kini kan ayafi ohun ti Won fi ranse si mi ni imisi.” So pe: "Nje afoju ati oluriran dogba bi? Se e o ronu jinle ni
وَأَنْذِرْ بِهِ الَّذِينَ يَخَافُونَ أَنْ يُحْشَرُوا إِلَىٰ رَبِّهِمْ ۙ لَيْسَ لَهُمْ مِنْ دُونِهِ وَلِيٌّ وَلَا شَفِيعٌ لَعَلَّهُمْ يَتَّقُونَ
Fi (al-Ƙur’an) se ikilo fun awon t’o n paya pe Won maa ko awon jo si odo Oluwa won, ko si nii si alaabo tabi olusipe kan fun won leyin Re. (Kilo fun won) ki won le beru (Allahu)
وَلَا تَطْرُدِ الَّذِينَ يَدْعُونَ رَبَّهُمْ بِالْغَدَاةِ وَالْعَشِيِّ يُرِيدُونَ وَجْهَهُ ۖ مَا عَلَيْكَ مِنْ حِسَابِهِمْ مِنْ شَيْءٍ وَمَا مِنْ حِسَابِكَ عَلَيْهِمْ مِنْ شَيْءٍ فَتَطْرُدَهُمْ فَتَكُونَ مِنَ الظَّالِمِينَ
Ma se le awon t’o n pe Oluwa won ni owuro ati ni asale danu; won n fe Oju rere Re ni. Isiro-ise won ko si ni orun re ni ona kan kan. Ko si si isiro-ise tire naa ni orun won ni ona kan kan. Ti o ba le won danu, o si maa wa ninu awon alabosi

Choose other languages: