Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anaam Ayahs #25 Translated in Yoruba

وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنِ افْتَرَىٰ عَلَى اللَّهِ كَذِبًا أَوْ كَذَّبَ بِآيَاتِهِ ۗ إِنَّهُ لَا يُفْلِحُ الظَّالِمُونَ
Ta l’o si sabosi ju eni ti o da adapa iro mo Allahu tabi (eni ti) o pe awon ayah Re niro? Dajudaju awon alabosi ko nii jere
وَيَوْمَ نَحْشُرُهُمْ جَمِيعًا ثُمَّ نَقُولُ لِلَّذِينَ أَشْرَكُوا أَيْنَ شُرَكَاؤُكُمُ الَّذِينَ كُنْتُمْ تَزْعُمُونَ
Ati pe (ranti) Ojo ti A oo ko gbogbo won jo patapata, leyin naa A oo so fun awon t’o ba (Allahu) wa akegbe pe: “Nibo ni awon orisa yin wa, awon ti e n so nipa won lai ni eri lowo pe won je akegbe Allahu?”
ثُمَّ لَمْ تَكُنْ فِتْنَتُهُمْ إِلَّا أَنْ قَالُوا وَاللَّهِ رَبِّنَا مَا كُنَّا مُشْرِكِينَ
Leyin naa, ifooro won (lori ibeere naa) ko je kini kan tayo pe won a wi pe: “A fi Allahu, Oluwa wa bura, awa ki i se osebo.”
انْظُرْ كَيْفَ كَذَبُوا عَلَىٰ أَنْفُسِهِمْ ۚ وَضَلَّ عَنْهُمْ مَا كَانُوا يَفْتَرُونَ
Wo bi won se paro mora won. Ohun ti won n da ni adapa iro si dofo mo won lowo
وَمِنْهُمْ مَنْ يَسْتَمِعُ إِلَيْكَ ۖ وَجَعَلْنَا عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ أَكِنَّةً أَنْ يَفْقَهُوهُ وَفِي آذَانِهِمْ وَقْرًا ۚ وَإِنْ يَرَوْا كُلَّ آيَةٍ لَا يُؤْمِنُوا بِهَا ۚ حَتَّىٰ إِذَا جَاءُوكَ يُجَادِلُونَكَ يَقُولُ الَّذِينَ كَفَرُوا إِنْ هَٰذَا إِلَّا أَسَاطِيرُ الْأَوَّلِينَ
Eni ti n gbo oro ni odo re n be ninu won. A si fi ebibo bo okan won ki won ma baa gbo agboye re. (A tun fi) edidi sinu eti won. Ti won ba ri gbogbo ami, won ko nii gba a gbo debi pe nigba ti won ba wa ba o, won yo si maa ba o jiyan; awon t’o sai gbagbo si maa wi pe: “Ki ni eyi bi ko se akosile alo awon eni akoko.”

Choose other languages: