Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #119 Translated in Yoruba

وَمَا يَفْعَلُوا مِنْ خَيْرٍ فَلَنْ يُكْفَرُوهُ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ بِالْمُتَّقِينَ
Ohunkohun ti won ba se ni ise rere, A o nii je ki won padanu esan re. Allahu si ni Onimo nipa awon oluberu (Re)
إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا لَنْ تُغْنِيَ عَنْهُمْ أَمْوَالُهُمْ وَلَا أَوْلَادُهُمْ مِنَ اللَّهِ شَيْئًا ۖ وَأُولَٰئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ ۚ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ
Dajudaju awon t’o sai gbagbo, awon dukia won ati awon omo won ko nii ro won loro kini kan nibi iya lodo Allahu. Awon wonyen si ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re
مَثَلُ مَا يُنْفِقُونَ فِي هَٰذِهِ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا كَمَثَلِ رِيحٍ فِيهَا صِرٌّ أَصَابَتْ حَرْثَ قَوْمٍ ظَلَمُوا أَنْفُسَهُمْ فَأَهْلَكَتْهُ ۚ وَمَا ظَلَمَهُمُ اللَّهُ وَلَٰكِنْ أَنْفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ
Apejuwe ohun ti won n na ninu isemi aye yii da bi apejuwe afefe ti ategun otutu lile wa ninu re. O fe lu oko awon eniyan t’o se abosi s’ori ara won. O si pa a run. Allahu ko si se abosi si won, sugbon emi ara won ni won n sabosi si
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَتَّخِذُوا بِطَانَةً مِنْ دُونِكُمْ لَا يَأْلُونَكُمْ خَبَالًا وَدُّوا مَا عَنِتُّمْ قَدْ بَدَتِ الْبَغْضَاءُ مِنْ أَفْوَاهِهِمْ وَمَا تُخْفِي صُدُورُهُمْ أَكْبَرُ ۚ قَدْ بَيَّنَّا لَكُمُ الْآيَاتِ ۖ إِنْ كُنْتُمْ تَعْقِلُونَ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se mu alafinuhan kan yato si ara yin. Won ko nii gewo aburu kuru fun yin. Won si nifee si ohun ti o maa ko inira ba yin. Ikorira kuku ti foju han lati enu won. Ohun ti o si pamo sinu okan won tobi julo. A ti salaye awon ayah fun yin, ti eyin ba je onilaakaye
هَا أَنْتُمْ أُولَاءِ تُحِبُّونَهُمْ وَلَا يُحِبُّونَكُمْ وَتُؤْمِنُونَ بِالْكِتَابِ كُلِّهِ وَإِذَا لَقُوكُمْ قَالُوا آمَنَّا وَإِذَا خَلَوْا عَضُّوا عَلَيْكُمُ الْأَنَامِلَ مِنَ الْغَيْظِ ۚ قُلْ مُوتُوا بِغَيْظِكُمْ ۗ إِنَّ اللَّهَ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ
Kiye si i, eyin wonyi nifee won, awon ko si nifee yin. Eyin gbagbo ninu awon tira, gbogbo re (patapata). Nigba ti won ba si pade yin, won a wi pe: “Awa gbagbo.” Nigba ti o ba si ku awon nikan, won yoo maa deyin mo ika lori yin ni ti ibinu. So pe: “E ku pelu ibinu yin.” Dajudaju Allahu ni Onimo nipa ohun ti n be ninu awon igba-aya eda

Choose other languages: