Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #121 Translated in Yoruba

مَثَلُ مَا يُنْفِقُونَ فِي هَٰذِهِ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا كَمَثَلِ رِيحٍ فِيهَا صِرٌّ أَصَابَتْ حَرْثَ قَوْمٍ ظَلَمُوا أَنْفُسَهُمْ فَأَهْلَكَتْهُ ۚ وَمَا ظَلَمَهُمُ اللَّهُ وَلَٰكِنْ أَنْفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ
Apejuwe ohun ti won n na ninu isemi aye yii da bi apejuwe afefe ti ategun otutu lile wa ninu re. O fe lu oko awon eniyan t’o se abosi s’ori ara won. O si pa a run. Allahu ko si se abosi si won, sugbon emi ara won ni won n sabosi si
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَتَّخِذُوا بِطَانَةً مِنْ دُونِكُمْ لَا يَأْلُونَكُمْ خَبَالًا وَدُّوا مَا عَنِتُّمْ قَدْ بَدَتِ الْبَغْضَاءُ مِنْ أَفْوَاهِهِمْ وَمَا تُخْفِي صُدُورُهُمْ أَكْبَرُ ۚ قَدْ بَيَّنَّا لَكُمُ الْآيَاتِ ۖ إِنْ كُنْتُمْ تَعْقِلُونَ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se mu alafinuhan kan yato si ara yin. Won ko nii gewo aburu kuru fun yin. Won si nifee si ohun ti o maa ko inira ba yin. Ikorira kuku ti foju han lati enu won. Ohun ti o si pamo sinu okan won tobi julo. A ti salaye awon ayah fun yin, ti eyin ba je onilaakaye
هَا أَنْتُمْ أُولَاءِ تُحِبُّونَهُمْ وَلَا يُحِبُّونَكُمْ وَتُؤْمِنُونَ بِالْكِتَابِ كُلِّهِ وَإِذَا لَقُوكُمْ قَالُوا آمَنَّا وَإِذَا خَلَوْا عَضُّوا عَلَيْكُمُ الْأَنَامِلَ مِنَ الْغَيْظِ ۚ قُلْ مُوتُوا بِغَيْظِكُمْ ۗ إِنَّ اللَّهَ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ
Kiye si i, eyin wonyi nifee won, awon ko si nifee yin. Eyin gbagbo ninu awon tira, gbogbo re (patapata). Nigba ti won ba si pade yin, won a wi pe: “Awa gbagbo.” Nigba ti o ba si ku awon nikan, won yoo maa deyin mo ika lori yin ni ti ibinu. So pe: “E ku pelu ibinu yin.” Dajudaju Allahu ni Onimo nipa ohun ti n be ninu awon igba-aya eda
إِنْ تَمْسَسْكُمْ حَسَنَةٌ تَسُؤْهُمْ وَإِنْ تُصِبْكُمْ سَيِّئَةٌ يَفْرَحُوا بِهَا ۖ وَإِنْ تَصْبِرُوا وَتَتَّقُوا لَا يَضُرُّكُمْ كَيْدُهُمْ شَيْئًا ۗ إِنَّ اللَّهَ بِمَا يَعْمَلُونَ مُحِيطٌ
Ti daadaa kan ba kan yin, o maa ko ibanuje ba won. Ti aburu kan ba si sele si yin, won maa dunnu si i. Ti eyin ba se suuru, ti e si sora (fun won), ete won ko nii ko inira kan kan ba yin. Dajudaju Allahu ni Alamotan nipa ohun ti won n se nise
وَإِذْ غَدَوْتَ مِنْ أَهْلِكَ تُبَوِّئُ الْمُؤْمِنِينَ مَقَاعِدَ لِلْقِتَالِ ۗ وَاللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ
(Ranti) nigba ti o ji kuro lodo awon ara ile re ni idaji kutukutu, ti o si n fi aye ibujagun han awon onigbagbo ododo, Allahu ni Olugbo, Onimo

Choose other languages: