Quran Apps in many lanuages:

Surah Yusuf Ayahs #23 Translated in Yoruba

وَجَاءَتْ سَيَّارَةٌ فَأَرْسَلُوا وَارِدَهُمْ فَأَدْلَىٰ دَلْوَهُ ۖ قَالَ يَا بُشْرَىٰ هَٰذَا غُلَامٌ ۚ وَأَسَرُّوهُ بِضَاعَةً ۚ وَاللَّهُ عَلِيمٌ بِمَا يَعْمَلُونَ
Awon onirin-ajo kan si de. Won ran aponmi won (ni omi). O si ju doro re sinu kannga. (Yusuf si diro mo okun doro bo sita. Aponmi si) so pe: "Ire idunnu re e! Eyi ni omodekunrin." Won si fi pamo fun tita (bi oja). Allahu si ni Onimo nipa ohun ti won n se nise
وَشَرَوْهُ بِثَمَنٍ بَخْسٍ دَرَاهِمَ مَعْدُودَةٍ وَكَانُوا فِيهِ مِنَ الزَّاهِدِينَ
Won ta a ni edinwo pelu owo diriham t’o niye. Won si je eni t’o mu un bin-intin
وَقَالَ الَّذِي اشْتَرَاهُ مِنْ مِصْرَ لِامْرَأَتِهِ أَكْرِمِي مَثْوَاهُ عَسَىٰ أَنْ يَنْفَعَنَا أَوْ نَتَّخِذَهُ وَلَدًا ۚ وَكَذَٰلِكَ مَكَّنَّا لِيُوسُفَ فِي الْأَرْضِ وَلِنُعَلِّمَهُ مِنْ تَأْوِيلِ الْأَحَادِيثِ ۚ وَاللَّهُ غَالِبٌ عَلَىٰ أَمْرِهِ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ
Eni ti o ra a ni (ilu) Misro so fun aya re pe: “Se ibugbe re daadaa. O sunmo ki o wulo fun wa tabi ki a fi somo.” Bayen ni A se fi aye gba Yusuf lori ile. Ati pe ki A tun le fi itumo ala mo on. Allahu ni Olubori lori ase Re, sugbon opolopo eniyan ni ko mo
وَلَمَّا بَلَغَ أَشُدَّهُ آتَيْنَاهُ حُكْمًا وَعِلْمًا ۚ وَكَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ
Nigba ti o di gende tan, A fun un ni ogbon ijinle ati imo. Bayen ni A se n san awon oluse-rere ni esan rere
وَرَاوَدَتْهُ الَّتِي هُوَ فِي بَيْتِهَا عَنْ نَفْسِهِ وَغَلَّقَتِ الْأَبْوَابَ وَقَالَتْ هَيْتَ لَكَ ۚ قَالَ مَعَاذَ اللَّهِ ۖ إِنَّهُ رَبِّي أَحْسَنَ مَثْوَايَ ۖ إِنَّهُ لَا يُفْلِحُ الظَّالِمُونَ
Obinrin ti Yusuf wa ninu ile re si jireebe fun ere ife lodo re. O si ti gbogbo ilekun pa. O so pe: “Sunmo mi.” (Yusuf) so pe: “Mo sadi Allahu. Dajudaju oko re ni oga mi. O si se ibugbe mi daadaa. Dajudaju awon alabosi ko nii jere.”

Choose other languages: