Quran Apps in many lanuages:

Surah Yunus Ayahs #90 Translated in Yoruba

وَنَجِّنَا بِرَحْمَتِكَ مِنَ الْقَوْمِ الْكَافِرِينَ
Ki O si fi aanu Re gba wa la lowo ijo alaigbagbo
وَأَوْحَيْنَا إِلَىٰ مُوسَىٰ وَأَخِيهِ أَنْ تَبَوَّآ لِقَوْمِكُمَا بِمِصْرَ بُيُوتًا وَاجْعَلُوا بُيُوتَكُمْ قِبْلَةً وَأَقِيمُوا الصَّلَاةَ ۗ وَبَشِّرِ الْمُؤْمِنِينَ
A si ranse si (Anabi) Musa ati arakunrin re pe: “Ki eyin mejeeji mu awon ibugbe fun awon eniyan yin si ilu Misro. Ki e si so ibugbe yin di ibukirun. Ki e si maa kirun. Ati pe, fun awon onigbagbo ododo ni iro idunnu.”
وَقَالَ مُوسَىٰ رَبَّنَا إِنَّكَ آتَيْتَ فِرْعَوْنَ وَمَلَأَهُ زِينَةً وَأَمْوَالًا فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا رَبَّنَا لِيُضِلُّوا عَنْ سَبِيلِكَ ۖ رَبَّنَا اطْمِسْ عَلَىٰ أَمْوَالِهِمْ وَاشْدُدْ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ فَلَا يُؤْمِنُوا حَتَّىٰ يَرَوُا الْعَذَابَ الْأَلِيمَ
(Anabi) Musa so pe: "Oluwa wa, dajudaju Iwo l’O fun Fir‘aon ati awon ijoye re ni oso ati dukia ninu isemi aye. Oluwa wa, (O fun won) nitori ki won le seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Re. Oluwa wa, pa dukia won re, ki O si mu okan won le, ki won ma gbagbo mo titi won fi maa ri iya eleta-elero
قَالَ قَدْ أُجِيبَتْ دَعْوَتُكُمَا فَاسْتَقِيمَا وَلَا تَتَّبِعَانِّ سَبِيلَ الَّذِينَ لَا يَعْلَمُونَ
(Allahu) so pe: "Dajudaju Mo ti gba adua eyin mejeeji. Nitori naa, ki eyin mejeeji duro sinsin. E ma se tele oju ona awon ti ko nimo
وَجَاوَزْنَا بِبَنِي إِسْرَائِيلَ الْبَحْرَ فَأَتْبَعَهُمْ فِرْعَوْنُ وَجُنُودُهُ بَغْيًا وَعَدْوًا ۖ حَتَّىٰ إِذَا أَدْرَكَهُ الْغَرَقُ قَالَ آمَنْتُ أَنَّهُ لَا إِلَٰهَ إِلَّا الَّذِي آمَنَتْ بِهِ بَنُو إِسْرَائِيلَ وَأَنَا مِنَ الْمُسْلِمِينَ
A mu awon omo ’Isro’il la agbami odo ja. Fir‘aon ati awon omo ogun re si gba to won leyin, ni ti abosi ati itayo enu-ala, titi iteri sinu agbami okun fi ba a. O si wi pe: “Mo gbagbo pe dajudaju ko si olohun ti ijosin to si afi Eni ti awon omo ’Isro’il gbagbo. Mo si wa ninu awon musulumi.”

Choose other languages: