Quran Apps in many lanuages:

Surah Yunus Ayahs #34 Translated in Yoruba

هُنَالِكَ تَبْلُو كُلُّ نَفْسٍ مَا أَسْلَفَتْ ۚ وَرُدُّوا إِلَى اللَّهِ مَوْلَاهُمُ الْحَقِّ ۖ وَضَلَّ عَنْهُمْ مَا كَانُوا يَفْتَرُونَ
Nibe yen, emi kookan maa da ohun t’o se siwaju mo. Won yo si da won pada sodo Allahu, Oluwa won, Ododo. Ohun ti won si n da ni adapa iro si maa dofo mo won lowo
قُلْ مَنْ يَرْزُقُكُمْ مِنَ السَّمَاءِ وَالْأَرْضِ أَمَّنْ يَمْلِكُ السَّمْعَ وَالْأَبْصَارَ وَمَنْ يُخْرِجُ الْحَيَّ مِنَ الْمَيِّتِ وَيُخْرِجُ الْمَيِّتَ مِنَ الْحَيِّ وَمَنْ يُدَبِّرُ الْأَمْرَ ۚ فَسَيَقُولُونَ اللَّهُ ۚ فَقُلْ أَفَلَا تَتَّقُونَ
So pe: “Ta ni O n pese fun yin lati inu sanmo ati ile? Ta ni O ni ikapa lori igboro ati iriran? Ta ni O n mu alaaye jade lati ara oku, ti O tun n mu oku jade lati ara alaaye? Ta si ni O n se eto oro (eda)?” Won yoo wi pe: "Allahu" Nigba naa, so pe: "Se e o nii beru (Re) ni
فَذَٰلِكُمُ اللَّهُ رَبُّكُمُ الْحَقُّ ۖ فَمَاذَا بَعْدَ الْحَقِّ إِلَّا الضَّلَالُ ۖ فَأَنَّىٰ تُصْرَفُونَ
Iyen ni Allahu, Oluwa yin, Ododo. Ki si ni o n be leyin Ododo bi ko se isina? Nitori naa, bawo ni won se n seri yin kuro nibi ododo
كَذَٰلِكَ حَقَّتْ كَلِمَتُ رَبِّكَ عَلَى الَّذِينَ فَسَقُوا أَنَّهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ
Bayen ni oro Oluwa re se wa si imuse lori awon t’o sebaje pe dajudaju won ko nii gbagbo
قُلْ هَلْ مِنْ شُرَكَائِكُمْ مَنْ يَبْدَأُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ ۚ قُلِ اللَّهُ يَبْدَأُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ ۖ فَأَنَّىٰ تُؤْفَكُونَ
So pe: "Nje o wa ninu awon orisa yin eni ti o le pile dida eda, leyin naa, ti o maa da a pada (si ipile re leyin iku)?" So pe: "Allahu l’O n pile dida eda. Leyin naa, O maa da a pada (si ipile re leyin iku). Nitori naa, bawo ni won se n seri yin kuro nibi ododo

Choose other languages: