Quran Apps in many lanuages:

Surah Yunus Ayahs #27 Translated in Yoruba

فَلَمَّا أَنْجَاهُمْ إِذَا هُمْ يَبْغُونَ فِي الْأَرْضِ بِغَيْرِ الْحَقِّ ۗ يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنَّمَا بَغْيُكُمْ عَلَىٰ أَنْفُسِكُمْ ۖ مَتَاعَ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۖ ثُمَّ إِلَيْنَا مَرْجِعُكُمْ فَنُنَبِّئُكُمْ بِمَا كُنْتُمْ تَعْمَلُونَ
Sugbon nigba ti O gba won la tan igba naa ni won tun n se ibaje kiri lori ile lai letoo. Eyin eniyan, dajudaju ibaje yin n be lori yin. (Ibaje yin si je) igbadun isemi aye. Leyin naa, odo Wa ni ibupadasi yin. A si maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise
إِنَّمَا مَثَلُ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا كَمَاءٍ أَنْزَلْنَاهُ مِنَ السَّمَاءِ فَاخْتَلَطَ بِهِ نَبَاتُ الْأَرْضِ مِمَّا يَأْكُلُ النَّاسُ وَالْأَنْعَامُ حَتَّىٰ إِذَا أَخَذَتِ الْأَرْضُ زُخْرُفَهَا وَازَّيَّنَتْ وَظَنَّ أَهْلُهَا أَنَّهُمْ قَادِرُونَ عَلَيْهَا أَتَاهَا أَمْرُنَا لَيْلًا أَوْ نَهَارًا فَجَعَلْنَاهَا حَصِيدًا كَأَنْ لَمْ تَغْنَ بِالْأَمْسِ ۚ كَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ الْآيَاتِ لِقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ
Apejuwe isemi aye da bi omi kan ti A sokale lati sanmo, ti awon irugbin ninu ohun ti eniyan ati awon eran-osin n je si gba a sara, titi di igba ti ile yoo fi loraa. O si mu oso (ara) re jade. Awon t’o ni i si lero pe awon ni alagbara lori re, (nigba naa ni) ase Wa de ba a ni oru tabi ni osan. A si so o di oko ti won fa tu danu bi eni pe ko si nibe rara ri ni ana. Bayen ni A se n salaye awon ayah fun ijo alarojinle
وَاللَّهُ يَدْعُو إِلَىٰ دَارِ السَّلَامِ وَيَهْدِي مَنْ يَشَاءُ إِلَىٰ صِرَاطٍ مُسْتَقِيمٍ
Allahu n pepe si ile Alaafia. O si n to eni ti O ba fe si ona taara (’Islam)
لِلَّذِينَ أَحْسَنُوا الْحُسْنَىٰ وَزِيَادَةٌ ۖ وَلَا يَرْهَقُ وُجُوهَهُمْ قَتَرٌ وَلَا ذِلَّةٌ ۚ أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ الْجَنَّةِ ۖ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ
Rere ati alekun (oore) wa fun awon t’o se rere. Eruku tabi iyepere kan ko nii bo won loju mole. Awon wonyen ni ero inu Ogba Idera. Olusegbere ni won ninu re
وَالَّذِينَ كَسَبُوا السَّيِّئَاتِ جَزَاءُ سَيِّئَةٍ بِمِثْلِهَا وَتَرْهَقُهُمْ ذِلَّةٌ ۖ مَا لَهُمْ مِنَ اللَّهِ مِنْ عَاصِمٍ ۖ كَأَنَّمَا أُغْشِيَتْ وُجُوهُهُمْ قِطَعًا مِنَ اللَّيْلِ مُظْلِمًا ۚ أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ ۖ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ
Awon t’o si s’ise aburu, esan aburu bi iru re (ni esan won). Iyepere si maa bo won mole. Ko si alaabo kan fun won lodo Allahu. (Won maa da bi) eni pe won fi apa kan oru t’o sokunkun bo won loju pa. Awon wonyen ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re

Choose other languages: