Quran Apps in many lanuages:

Surah Yunus Ayahs #23 Translated in Yoruba

وَمَا كَانَ النَّاسُ إِلَّا أُمَّةً وَاحِدَةً فَاخْتَلَفُوا ۚ وَلَوْلَا كَلِمَةٌ سَبَقَتْ مِنْ رَبِّكَ لَقُضِيَ بَيْنَهُمْ فِيمَا فِيهِ يَخْتَلِفُونَ
Ki ni awon eniyan je (ni ipile) bi ko se ijo eyo kan (ijo ’Islam). Leyin naa ni won yapa enu. Ti ko ba je pe oro kan t’o ti siwaju lodo Oluwa re, Awa iba ti yanju ohun ti won n yapa enu si laaarin ara won
وَيَقُولُونَ لَوْلَا أُنْزِلَ عَلَيْهِ آيَةٌ مِنْ رَبِّهِ ۖ فَقُلْ إِنَّمَا الْغَيْبُ لِلَّهِ فَانْتَظِرُوا إِنِّي مَعَكُمْ مِنَ الْمُنْتَظِرِينَ
Won n wi pe: “Ki ni ko je ki ami kan sokale fun un lati odo Oluwa re?” Nitori naa, so pe: “Ti Allahu ni ikoko. Nitori naa, e maa reti. Dajudaju emi naa wa pelu yin ninu awon olureti.”
وَإِذَا أَذَقْنَا النَّاسَ رَحْمَةً مِنْ بَعْدِ ضَرَّاءَ مَسَّتْهُمْ إِذَا لَهُمْ مَكْرٌ فِي آيَاتِنَا ۚ قُلِ اللَّهُ أَسْرَعُ مَكْرًا ۚ إِنَّ رُسُلَنَا يَكْتُبُونَ مَا تَمْكُرُونَ
Nigba ti A ba fun awon eniyan ni idera kan towo leyin ti inira ti fowo ba won, nigba naa ni won maa dete si awon ayah Wa. So pe: “Allahu yara julo nibi ete. Dajudaju awon Ojise Wa n se akosile ohun ti e n da lete.”
هُوَ الَّذِي يُسَيِّرُكُمْ فِي الْبَرِّ وَالْبَحْرِ ۖ حَتَّىٰ إِذَا كُنْتُمْ فِي الْفُلْكِ وَجَرَيْنَ بِهِمْ بِرِيحٍ طَيِّبَةٍ وَفَرِحُوا بِهَا جَاءَتْهَا رِيحٌ عَاصِفٌ وَجَاءَهُمُ الْمَوْجُ مِنْ كُلِّ مَكَانٍ وَظَنُّوا أَنَّهُمْ أُحِيطَ بِهِمْ ۙ دَعَوُا اللَّهَ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ لَئِنْ أَنْجَيْتَنَا مِنْ هَٰذِهِ لَنَكُونَنَّ مِنَ الشَّاكِرِينَ
(Allahu) Oun ni Eni ti O mu yin rin lori ile ati ni oju omi, titi di igba ti e ba wa ninu oko oju-omi, ti ategun t’o dara si n tuko won lo, inu won yo si maa dun si i. (Amo) ategun lile ko lu u, igbi omi de ba won ni gbogbo aye, won si lero pe dajudaju won ti fi (adanwo) yi awon po, won si pe Allahu pelu sise afomo-adua fun Un pe: “Dajudaju ti O ba fi le gba wa la nibi eyi, dajudaju a maa wa ninu awon oludupe.”
فَلَمَّا أَنْجَاهُمْ إِذَا هُمْ يَبْغُونَ فِي الْأَرْضِ بِغَيْرِ الْحَقِّ ۗ يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنَّمَا بَغْيُكُمْ عَلَىٰ أَنْفُسِكُمْ ۖ مَتَاعَ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۖ ثُمَّ إِلَيْنَا مَرْجِعُكُمْ فَنُنَبِّئُكُمْ بِمَا كُنْتُمْ تَعْمَلُونَ
Sugbon nigba ti O gba won la tan igba naa ni won tun n se ibaje kiri lori ile lai letoo. Eyin eniyan, dajudaju ibaje yin n be lori yin. (Ibaje yin si je) igbadun isemi aye. Leyin naa, odo Wa ni ibupadasi yin. A si maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise

Choose other languages: