Quran Apps in many lanuages:

Surah Ta-Ha Ayahs #44 Translated in Yoruba

إِذْ تَمْشِي أُخْتُكَ فَتَقُولُ هَلْ أَدُلُّكُمْ عَلَىٰ مَنْ يَكْفُلُهُ ۖ فَرَجَعْنَاكَ إِلَىٰ أُمِّكَ كَيْ تَقَرَّ عَيْنُهَا وَلَا تَحْزَنَ ۚ وَقَتَلْتَ نَفْسًا فَنَجَّيْنَاكَ مِنَ الْغَمِّ وَفَتَنَّاكَ فُتُونًا ۚ فَلَبِثْتَ سِنِينَ فِي أَهْلِ مَدْيَنَ ثُمَّ جِئْتَ عَلَىٰ قَدَرٍ يَا مُوسَىٰ
(Ranti) nigba ti arabinrin re n rin lo, o si so pe: “Se ki ng juwe eni ti o maa gba a to (fun yin)?” A si da o pada sodo iya re nitori ki o le ni itutu oju, ko si nii banuje. Ati pe o pa emi eni kan. A si mu o kuro ninu ibanuje. A tun mu awon adanwo kan ba o. O tun lo awon odun kan lodo awon ara Modyan. Leyin naa, o de (ni akoko) ti o ti wa ninu kadara, Musa
وَاصْطَنَعْتُكَ لِنَفْسِي
Mo si sa o lesa fun (ise) Mi
اذْهَبْ أَنْتَ وَأَخُوكَ بِآيَاتِي وَلَا تَنِيَا فِي ذِكْرِي
Lo, iwo ati arakunrin re, pelu awon ami (ise iyanu) Mi. Ki e si ma se kole ninu iranti Mi
اذْهَبَا إِلَىٰ فِرْعَوْنَ إِنَّهُ طَغَىٰ
E lo ba Fir‘aon. Dajudaju o ti tayo enu-ala
فَقُولَا لَهُ قَوْلًا لَيِّنًا لَعَلَّهُ يَتَذَكَّرُ أَوْ يَخْشَىٰ
E so oro ele fun un. O see se ki o lo isiti tabi ki o paya (Mi)

Choose other languages: