Quran Apps in many lanuages:

Surah Saba Ayahs #23 Translated in Yoruba

فَقَالُوا رَبَّنَا بَاعِدْ بَيْنَ أَسْفَارِنَا وَظَلَمُوا أَنْفُسَهُمْ فَجَعَلْنَاهُمْ أَحَادِيثَ وَمَزَّقْنَاهُمْ كُلَّ مُمَزَّقٍ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِكُلِّ صَبَّارٍ شَكُورٍ
(Awon ara ilu Saba’) wi pe: “Oluwa wa, mu awon irin-ajo wa lati ilu kan si ilu miiran jinna sira won.” Won se abosi si emi ara won. A si so won di itan. A si fon won ka patapata. Dajudaju awon ami kan wa ninu iyen fun gbogbo onisuuru, oludupe
وَلَقَدْ صَدَّقَ عَلَيْهِمْ إِبْلِيسُ ظَنَّهُ فَاتَّبَعُوهُ إِلَّا فَرِيقًا مِنَ الْمُؤْمِنِينَ
Dajudaju ’Iblis ti so aba re di ododo le won lori. Won si tele e afi igun kan ninu awon onigbagbo ododo
وَمَا كَانَ لَهُ عَلَيْهِمْ مِنْ سُلْطَانٍ إِلَّا لِنَعْلَمَ مَنْ يُؤْمِنُ بِالْآخِرَةِ مِمَّنْ هُوَ مِنْهَا فِي شَكٍّ ۗ وَرَبُّكَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ حَفِيظٌ
(’Iblis) ko si ni agbara kan lori won bi ko se pe ki A le safi han eni t’o gba Ojo Ikeyin gbo kuro lara eni t’o wa ninu iyemeji nipa re. Oluso si ni Oluwa re lori gbogbo nnkan
قُلِ ادْعُوا الَّذِينَ زَعَمْتُمْ مِنْ دُونِ اللَّهِ ۖ لَا يَمْلِكُونَ مِثْقَالَ ذَرَّةٍ فِي السَّمَاوَاتِ وَلَا فِي الْأَرْضِ وَمَا لَهُمْ فِيهِمَا مِنْ شِرْكٍ وَمَا لَهُ مِنْهُمْ مِنْ ظَهِيرٍ
So pe: “E pe awon ti e so pe (won je oluwa) leyin Allahu.” Won ko ni ikapa odiwon omo-ina igun ninu sanmo tabi ninu ile. Won ko si ni ipin kan ninu mejeeji. Ati pe ko si oluranlowo kan fun Allahu laaarin won
وَلَا تَنْفَعُ الشَّفَاعَةُ عِنْدَهُ إِلَّا لِمَنْ أَذِنَ لَهُ ۚ حَتَّىٰ إِذَا فُزِّعَ عَنْ قُلُوبِهِمْ قَالُوا مَاذَا قَالَ رَبُّكُمْ ۖ قَالُوا الْحَقَّ ۖ وَهُوَ الْعَلِيُّ الْكَبِيرُ
Isipe ko si nii sanfaani lodo Allahu afi fun eni ti O ba yonda fun. (Inufu-ayafu ni awon olusipe ati awon olusipe-fun maa wa) titi A oo fi yo ijaya kuro ninu okan won. Won si maa so (fun awon molaika) pe: “Ki ni Oluwa yin so (ni esi isipe)?” Won maa so pe: “Ododo l’O so (isipe yin ti wole. Allahu) Oun l’O ga, O tobi

Choose other languages: