Quran Apps in many lanuages:

Surah Ibrahim Ayahs #48 Translated in Yoruba

وَأَنْذِرِ النَّاسَ يَوْمَ يَأْتِيهِمُ الْعَذَابُ فَيَقُولُ الَّذِينَ ظَلَمُوا رَبَّنَا أَخِّرْنَا إِلَىٰ أَجَلٍ قَرِيبٍ نُجِبْ دَعْوَتَكَ وَنَتَّبِعِ الرُّسُلَ ۗ أَوَلَمْ تَكُونُوا أَقْسَمْتُمْ مِنْ قَبْلُ مَا لَكُمْ مِنْ زَوَالٍ
Kilo fun awon eniyan nipa ojo ti iya yoo de ba won, awon t’o sabosi yo si wi pe: “Oluwa wa, lo wa lara fun asiko die si i, a maa jepe Re, a si maa tele awon Ojise.” Se eyin ko ti bura siwaju pe eyin ko nii kuro nile aye ni
وَسَكَنْتُمْ فِي مَسَاكِنِ الَّذِينَ ظَلَمُوا أَنْفُسَهُمْ وَتَبَيَّنَ لَكُمْ كَيْفَ فَعَلْنَا بِهِمْ وَضَرَبْنَا لَكُمُ الْأَمْثَالَ
E si gbe ninu ibugbe awon t’o sabosi si emi ara won. O si han si yin bi A ti se pelu won. A tun fun yin ni awon akawe
وَقَدْ مَكَرُوا مَكْرَهُمْ وَعِنْدَ اللَّهِ مَكْرُهُمْ وَإِنْ كَانَ مَكْرُهُمْ لِتَزُولَ مِنْهُ الْجِبَالُ
Won kuku ti da ete won, odo Allahu si ni ete won wa, bi o tile je pe (pelu) ete won apata fee le ye lule
فَلَا تَحْسَبَنَّ اللَّهَ مُخْلِفَ وَعْدِهِ رُسُلَهُ ۗ إِنَّ اللَّهَ عَزِيزٌ ذُو انْتِقَامٍ
Nitori naa, ma se lero pe Allahu yoo yapa adehun Re ti O se fun awon Ojise Re. Dajudaju Allahu ni Alagbara, Olugbesan
يَوْمَ تُبَدَّلُ الْأَرْضُ غَيْرَ الْأَرْضِ وَالسَّمَاوَاتُ ۖ وَبَرَزُوا لِلَّهِ الْوَاحِدِ الْقَهَّارِ
Ni ojo ti A maa yi ile aye pada si nnkan miiran. (A maa yi) awon sanmo naa (pada. Awon eda) si maa jade (siwaju) Allahu, Okan soso, Olubori

Choose other languages: