Quran Apps in many lanuages:

Surah Hud Ayahs #67 Translated in Yoruba

قَالَ يَا قَوْمِ أَرَأَيْتُمْ إِنْ كُنْتُ عَلَىٰ بَيِّنَةٍ مِنْ رَبِّي وَآتَانِي مِنْهُ رَحْمَةً فَمَنْ يَنْصُرُنِي مِنَ اللَّهِ إِنْ عَصَيْتُهُ ۖ فَمَا تَزِيدُونَنِي غَيْرَ تَخْسِيرٍ
O so pe: "Eyin ijo mi, e so fun mi, ti o ba je pe emi wa lori eri t’o yanju lati odo Oluwa mi, ti ike kan si de ba mi lati odo Re, ta ni eni ti o maa ran mi lowo ninu (iya) Allahu ti mo ba yapa Re? Ko si kini kan ti e le fi se alekun re fun mi yato si iparun
وَيَا قَوْمِ هَٰذِهِ نَاقَةُ اللَّهِ لَكُمْ آيَةً فَذَرُوهَا تَأْكُلْ فِي أَرْضِ اللَّهِ وَلَا تَمَسُّوهَا بِسُوءٍ فَيَأْخُذَكُمْ عَذَابٌ قَرِيبٌ
Eyin ijo mi, eyi ni abo rakunmi Allahu. O je ami fun yin. Nitori naa, e fi sile, ki o maa je kiri lori ile Allahu. E ma se fi inira kan an nitori ki iya t’o sunmo ma baa je yin
فَعَقَرُوهَا فَقَالَ تَمَتَّعُوا فِي دَارِكُمْ ثَلَاثَةَ أَيَّامٍ ۖ ذَٰلِكَ وَعْدٌ غَيْرُ مَكْذُوبٍ
Won si gun un pa. O so pe: “E jegbadun ninu ile yin fun ojo meta (ki iya yin to de). Iyen ni adehun ti ki i se iro.”
فَلَمَّا جَاءَ أَمْرُنَا نَجَّيْنَا صَالِحًا وَالَّذِينَ آمَنُوا مَعَهُ بِرَحْمَةٍ مِنَّا وَمِنْ خِزْيِ يَوْمِئِذٍ ۗ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ الْقَوِيُّ الْعَزِيزُ
Nigba ti ase Wa de, A gba (Anabi) Solih ati awon t’o gbagbo pelu re la pelu ike lati odo Wa. (A tun gba won la) ninu abuku ojo yen. Dajudaju Oluwa Re, Oun ni Alagbara, Olubori (eda)
وَأَخَذَ الَّذِينَ ظَلَمُوا الصَّيْحَةُ فَأَصْبَحُوا فِي دِيَارِهِمْ جَاثِمِينَ
Ohun igbe lile gba awon t’o sabosi mu. Won si di eni t’o da lule, ti won ti doku sinu ilu won

Choose other languages: