Quran Apps in many lanuages:

Surah Hud Ayahs #70 Translated in Yoruba

فَلَمَّا جَاءَ أَمْرُنَا نَجَّيْنَا صَالِحًا وَالَّذِينَ آمَنُوا مَعَهُ بِرَحْمَةٍ مِنَّا وَمِنْ خِزْيِ يَوْمِئِذٍ ۗ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ الْقَوِيُّ الْعَزِيزُ
Nigba ti ase Wa de, A gba (Anabi) Solih ati awon t’o gbagbo pelu re la pelu ike lati odo Wa. (A tun gba won la) ninu abuku ojo yen. Dajudaju Oluwa Re, Oun ni Alagbara, Olubori (eda)
وَأَخَذَ الَّذِينَ ظَلَمُوا الصَّيْحَةُ فَأَصْبَحُوا فِي دِيَارِهِمْ جَاثِمِينَ
Ohun igbe lile gba awon t’o sabosi mu. Won si di eni t’o da lule, ti won ti doku sinu ilu won
كَأَنْ لَمْ يَغْنَوْا فِيهَا ۗ أَلَا إِنَّ ثَمُودَ كَفَرُوا رَبَّهُمْ ۗ أَلَا بُعْدًا لِثَمُودَ
Afi bi eni pe won ko gbenu ilu naa ri. Gbo, dajudaju iran Thamud sai gbagbo ninu Oluwa won. Kiye si i, ijinna rere si ike n be fun ijo Thamud
وَلَقَدْ جَاءَتْ رُسُلُنَا إِبْرَاهِيمَ بِالْبُشْرَىٰ قَالُوا سَلَامًا ۖ قَالَ سَلَامٌ ۖ فَمَا لَبِثَ أَنْ جَاءَ بِعِجْلٍ حَنِيذٍ
Dajudaju awon Ojise Wa ti mu iro idunnu wa ba (Anabi) ’Ibrohim. Won so pe: “Alaafia (fun o).” O so pe: “Alaafia (fun yin).” Ko si pe rara t’o fi gbe omo maalu ayangbe wa
فَلَمَّا رَأَىٰ أَيْدِيَهُمْ لَا تَصِلُ إِلَيْهِ نَكِرَهُمْ وَأَوْجَسَ مِنْهُمْ خِيفَةً ۚ قَالُوا لَا تَخَفْ إِنَّا أُرْسِلْنَا إِلَىٰ قَوْمِ لُوطٍ
Nigba ti o ri owo won pe ko kan ounje, o f’oju odi wo (aijeun) won. Iberu won si wa ninu okan re. Won so pe: “Ma se beru. Dajudaju awon eniyan (Anabi) Lut ni Won ran awa si.”

Choose other languages: