Quran Apps in many lanuages:

Surah Hud Ayahs #73 Translated in Yoruba

وَلَقَدْ جَاءَتْ رُسُلُنَا إِبْرَاهِيمَ بِالْبُشْرَىٰ قَالُوا سَلَامًا ۖ قَالَ سَلَامٌ ۖ فَمَا لَبِثَ أَنْ جَاءَ بِعِجْلٍ حَنِيذٍ
Dajudaju awon Ojise Wa ti mu iro idunnu wa ba (Anabi) ’Ibrohim. Won so pe: “Alaafia (fun o).” O so pe: “Alaafia (fun yin).” Ko si pe rara t’o fi gbe omo maalu ayangbe wa
فَلَمَّا رَأَىٰ أَيْدِيَهُمْ لَا تَصِلُ إِلَيْهِ نَكِرَهُمْ وَأَوْجَسَ مِنْهُمْ خِيفَةً ۚ قَالُوا لَا تَخَفْ إِنَّا أُرْسِلْنَا إِلَىٰ قَوْمِ لُوطٍ
Nigba ti o ri owo won pe ko kan ounje, o f’oju odi wo (aijeun) won. Iberu won si wa ninu okan re. Won so pe: “Ma se beru. Dajudaju awon eniyan (Anabi) Lut ni Won ran awa si.”
وَامْرَأَتُهُ قَائِمَةٌ فَضَحِكَتْ فَبَشَّرْنَاهَا بِإِسْحَاقَ وَمِنْ وَرَاءِ إِسْحَاقَ يَعْقُوبَ
Iyawo re wa ni iduro, o rerin-in. A si fun un ni iro idunnu (pe o maa bi) ’Ishaƙ. Ati pe leyin ’Ishaƙ ni Ya‘ƙub (iyen, omoomo)
قَالَتْ يَا وَيْلَتَىٰ أَأَلِدُ وَأَنَا عَجُوزٌ وَهَٰذَا بَعْلِي شَيْخًا ۖ إِنَّ هَٰذَا لَشَيْءٌ عَجِيبٌ
O so pe: “Hen-en! Se pe mo maa bimo? Arugbobinrin ni mi, baale mi yii si ti dagbalagba! Dajudaju eyi ni nnkan iyanu.”
قَالُوا أَتَعْجَبِينَ مِنْ أَمْرِ اللَّهِ ۖ رَحْمَتُ اللَّهِ وَبَرَكَاتُهُ عَلَيْكُمْ أَهْلَ الْبَيْتِ ۚ إِنَّهُ حَمِيدٌ مَجِيدٌ
Won so pe: “Se o maa seemo nipa ase Allahu ni? Ike Allahu ati ibukun Re ki o maa be fun yin, eyin ara ile (yii). Dajudaju Allahu ni Olope, Eleyin.”

Choose other languages: