Quran Apps in many lanuages:

Surah Hud Ayahs #47 Translated in Yoruba

قَالَ سَآوِي إِلَىٰ جَبَلٍ يَعْصِمُنِي مِنَ الْمَاءِ ۚ قَالَ لَا عَاصِمَ الْيَوْمَ مِنْ أَمْرِ اللَّهِ إِلَّا مَنْ رَحِمَ ۚ وَحَالَ بَيْنَهُمَا الْمَوْجُ فَكَانَ مِنَ الْمُغْرَقِينَ
O wi pe: “Emi yoo fori pamo sibi apata kan ti o maa la mi nibi omi.” (Anabi Nuh) so pe: "Ko si alaabo kan ni oni nibi ase Allahu afi eni ti Allahu ba saanu." Igbi omi si la awon mejeeji laaarin. O si di ara awon oluteri sinu omi
وَقِيلَ يَا أَرْضُ ابْلَعِي مَاءَكِ وَيَا سَمَاءُ أَقْلِعِي وَغِيضَ الْمَاءُ وَقُضِيَ الْأَمْرُ وَاسْتَوَتْ عَلَى الْجُودِيِّ ۖ وَقِيلَ بُعْدًا لِلْقَوْمِ الظَّالِمِينَ
A so pe: "Ile, fa omi re mu. Sanmo, dawo (ojo) duro." Won si din omi ku. Oro iparun won si wa si imuse. (Oko oju-omi) si gunle sori apata Judi. A si so pe: “Ijinna rere si ike Allahu ni ti ijo alabosi.”
وَنَادَىٰ نُوحٌ رَبَّهُ فَقَالَ رَبِّ إِنَّ ابْنِي مِنْ أَهْلِي وَإِنَّ وَعْدَكَ الْحَقُّ وَأَنْتَ أَحْكَمُ الْحَاكِمِينَ
(Anabi) Nuh pe Oluwa re, o si so pe: “Oluwa mi, dajudaju omo mi wa ninu ara ile mi. Ati pe dajudaju adehun Re, ododo ni. Iwo l’O si mo ejo da julo ninu awon adajo
قَالَ يَا نُوحُ إِنَّهُ لَيْسَ مِنْ أَهْلِكَ ۖ إِنَّهُ عَمَلٌ غَيْرُ صَالِحٍ ۖ فَلَا تَسْأَلْنِ مَا لَيْسَ لَكَ بِهِ عِلْمٌ ۖ إِنِّي أَعِظُكَ أَنْ تَكُونَ مِنَ الْجَاهِلِينَ
Allahu so pe: “Nuh, dajudaju ko si ninu ara ile re (ni ti esin). Dajudaju ise ti ko dara ni. Nitori naa, o o gbodo bi Mi leere nnkan ti o o ni imo nipa re. Dajudaju Emi n kilo fun o nitori ki o ma baa di ara awon alaimokan.”
قَالَ رَبِّ إِنِّي أَعُوذُ بِكَ أَنْ أَسْأَلَكَ مَا لَيْسَ لِي بِهِ عِلْمٌ ۖ وَإِلَّا تَغْفِرْ لِي وَتَرْحَمْنِي أَكُنْ مِنَ الْخَاسِرِينَ
O so pe: "Oluwa mi, dajudaju emi n sa di O nibi ki ng bi O leere nnkan ti emi ko ni imo re. Ti O o ba forijin mi, ki O si saanu mi, emi yoo wa lara awon eni ofo

Choose other languages: