Quran Apps in many lanuages:

Surah Hud Ayahs #113 Translated in Yoruba

فَلَا تَكُ فِي مِرْيَةٍ مِمَّا يَعْبُدُ هَٰؤُلَاءِ ۚ مَا يَعْبُدُونَ إِلَّا كَمَا يَعْبُدُ آبَاؤُهُمْ مِنْ قَبْلُ ۚ وَإِنَّا لَمُوَفُّوهُمْ نَصِيبَهُمْ غَيْرَ مَنْقُوصٍ
Nitori naa, ma se wa ninu royiroyi nipa ohun ti awon wonyi n josin fun. Won ko josin fun kini kan bi ko se bi awon baba won naa se n josin (fun awon orisa) ni isaaju. Dajudaju Awa yoo san won ni esan ipin (iya) won lai nii ku sibi kan
وَلَقَدْ آتَيْنَا مُوسَى الْكِتَابَ فَاخْتُلِفَ فِيهِ ۚ وَلَوْلَا كَلِمَةٌ سَبَقَتْ مِنْ رَبِّكَ لَقُضِيَ بَيْنَهُمْ ۚ وَإِنَّهُمْ لَفِي شَكٍّ مِنْهُ مُرِيبٍ
A kuku fun (Anabi) Musa ni Tira. Won si yapa enu nipa re. Ati pe ti ki i ba se oro kan ti o ti gbawaju lati odo Oluwa re ni, Awa iba ti sedajo laaarin won. Dajudaju won kuku wa ninu iyemeji t’o gbopon nipa al-Ƙur’an
وَإِنَّ كُلًّا لَمَّا لَيُوَفِّيَنَّهُمْ رَبُّكَ أَعْمَالَهُمْ ۚ إِنَّهُ بِمَا يَعْمَلُونَ خَبِيرٌ
Dajudaju eni kookan won ni Oluwa re yoo san ni esan ise won. Dajudaju Oun ni Alamotan nipa ohun ti won n se nise
فَاسْتَقِمْ كَمَا أُمِرْتَ وَمَنْ تَابَ مَعَكَ وَلَا تَطْغَوْا ۚ إِنَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ
Duro sinsin gege bi A se pa iwo ati enikeni ti o ba ronu piwada pelu re lase. E ma se tayo enu-ala. Dajudaju Oun ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise
وَلَا تَرْكَنُوا إِلَى الَّذِينَ ظَلَمُوا فَتَمَسَّكُمُ النَّارُ وَمَا لَكُمْ مِنْ دُونِ اللَّهِ مِنْ أَوْلِيَاءَ ثُمَّ لَا تُنْصَرُونَ
E ma se te sodo awon t’o sabosi nitori ki Ina ma baa fowo ba yin. Ko si nii si awon alaabo fun yin leyin Allahu. Leyin naa, A o nii ran yin lowo

Choose other languages: